3 Bákan náà, tí mo bá lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, màá tún pa dà wá, màá sì gbà yín sílé sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ̀yin náà lè wà ní ibi tí mo wà.+
24 Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fún mi wà pẹ̀lú mi níbi tí mo bá wà,+ kí wọ́n lè rí ògo mi tí o ti fún mi, torí pé o ti nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú kí o tó pilẹ̀ ayé.+
23 Mi ò mọ èyí tí màá mú nínú nǹkan méjì tó wà níwájú mi yìí, torí ó wù mí kí n gba ìtúsílẹ̀, kí n sì wà pẹ̀lú Kristi,+ torí ó dájú pé, ìyẹn ló sàn jù.+
6 Aláyọ̀ àti ẹni mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́;+ ikú kejì+ kò ní àṣẹ lórí wọn,+ àmọ́ wọ́n máa jẹ́ àlùfáà+ Ọlọ́run àti ti Kristi, wọ́n sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.+