-
Éfésù 6:14-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè,+ kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀,+ 15 pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a wọ̀ ní bàtà, kí ẹ lè fi ìmúratán kéde ìhìn rere àlàáfíà.+ 16 Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́,+ tí ẹ ó fi lè paná gbogbo ọfà* oníná ti ẹni burúkú náà.+ 17 Bákan náà, ẹ gba akoto* ìgbàlà+ àti idà ẹ̀mí, ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+
-