10 Bí wọ́n ṣe tẹjú mọ́ sánmà nígbà tó ń lọ, lójijì ọkùnrin méjì tó wọ aṣọ funfun+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 11 wọ́n sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Gálílì, kí ló dé tí ẹ dúró tí ẹ̀ ń wojú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ṣe rí i tó ń lọ sínú sánmà.”