36 Jésù dáhùn pé:+ “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.+ Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́.+ Àmọ́, bó ṣe rí yìí, Ìjọba mi ò wá láti orísun yìí.”
10 Torí náà, Pílátù sọ fún un pé: “Ṣé o ò fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ ni? Àbí o ò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti tú ọ sílẹ̀, mo sì tún ní àṣẹ láti pa ọ́?”*11 Jésù dá a lóhùn pé: “O ò lè ní àṣẹ kankan lórí mi àfi tí a bá fún ọ láṣẹ látòkè. Ìdí nìyẹn tí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin tó fi mí lé ọ lọ́wọ́ fi tóbi jù.”