44 “Ní ọjọ́ àwọn ọba yẹn, Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,+ tí kò ní pa run láé.+ A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì.+ Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú,+ ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé,+
14 A sì fún un ní àkóso,+ ọlá+ àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín.+ Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.+