9 Bákan náà, kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tó bójú mu ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀, kì í ṣe dídi irun lọ́nà àrà àti lílo wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ olówó ńlá,+ 10 àmọ́ kó jẹ́ lọ́nà tó yẹ àwọn obìnrin tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,+ ìyẹn nípa àwọn iṣẹ́ rere.