24 Torí pé kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́* sí gbogbo èèyàn,+ kí ó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni, kó máa kó ara rẹ̀ níjàánu tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa sí i,+
7 Torí pé alábòójútó jẹ́ ìríjú Ọlọ́run, kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sùn lọ́rùn, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀,+ kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń tètè bínú,+ kó má ṣe jẹ́ ọ̀mùtípara, kó má ṣe jẹ́ oníwà ipá,* kó má sì jẹ́ ẹni tó máa ń wá èrè tí kò tọ́,