3 Nígbà tó jókòó sórí Òkè Ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a ní òun nìkan, wọ́n sọ pé: “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín*+ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”*+
4Àmọ́, ọ̀rọ̀ onímìísí* sọ ní kedere pé tó bá yá àwọn kan máa yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n á máa tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí*+ tó ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù,
17 Àmọ́, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ rántí ọ̀rọ̀* tí àwọn àpọ́sítélì Olúwa wa Jésù Kristi ti sọ, 18 bí wọ́n ṣe máa ń sọ fún yín pé: “Ní àkókò ìkẹyìn, àwọn tó ń fini ṣe ẹlẹ́yà yóò wà, ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tó ń wù wọ́n ni wọ́n á máa ṣe.”+