2 Àmọ́, ẹ̀yin ará, ní ti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi+ àti kíkó wa jọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ a rọ̀ yín 2 kí ọkàn yín má tètè mì tàbí kí ó dà rú nítorí ọ̀rọ̀ onímìísí+ tàbí nítorí iṣẹ́ tí a fẹnu jẹ́ tàbí nítorí lẹ́tà kan tó dà bíi pé ó wá látọ̀dọ̀ wa, tó ń sọ pé ọjọ́ Jèhófà+ ti dé.