-
Léfítíkù 23:37, 38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 “‘Èyí ni àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ tó jẹ́ ti Jèhófà tí ẹ máa kéde pé wọ́n jẹ́ àpéjọ mímọ́,+ láti máa fi mú ọrẹ àfinásun wá fún Jèhófà: ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà+ tó jẹ́ ti ẹbọ àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ gẹ́gẹ́ bí ètò ojoojúmọ́. 38 Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àfikún sí ohun tí ẹ fi rúbọ ní àwọn sábáàtì Jèhófà+ àti àwọn ẹ̀bùn yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́+ àti àwọn ọrẹ àtinúwá yín,+ tí ẹ máa fún Jèhófà.
-