-
Ẹ́kísódù 24:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Mósè wá mú ìdajì lára ẹ̀jẹ̀ náà, ó dà á sínú àwọn abọ́, ó sì wọ́n ìdajì sórí pẹpẹ. 7 Lẹ́yìn náà, ó mú ìwé májẹ̀mú, ó kà á sókè fún àwọn èèyàn náà.+ Wọ́n sì sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe, a ó sì máa ṣègbọràn.”+ 8 Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn èèyàn náà,+ ó sì sọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ yìí.”+
-