12 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ,+ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn àjèjì yín tó ń gbé nínú àwọn ìlú yín, kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí.