-
Jẹ́nẹ́sísì 27:38-40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Ísọ̀ sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, ṣé ìbùkún kan ṣoṣo lo ní ni? Súre fún mi, bàbá mi, àní kí o súre fún èmi náà!” Ni Ísọ̀ bá ké, ó sì bú sẹ́kún.+ 39 Ísákì bàbá rẹ̀ wá sọ fún un pé:
“Wò ó, ibi tó jìnnà sí àwọn ilẹ̀ tó lọ́ràá ní ayé àti ibi tó jìnnà sí ìrì tó ń sẹ̀ láti ọ̀run ni wàá máa gbé.+ 40 Idà rẹ ni yóò máa mú ọ wà láàyè,+ àbúrò+ rẹ sì ni ìwọ yóò máa sìn. Àmọ́ tí o kò bá lè fara dà á mọ́, ó dájú pé wàá ṣẹ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”+
-