2 Jèhófà sọ pé, “Mo ti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.”+
Àmọ́, ẹ sọ pé: “Kí lo ṣe tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wa?”
Jèhófà sọ pé, “Ṣebí ọmọ ìyá ni Jékọ́bù àti Ísọ̀?+ Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù, 3 mo sì kórìíra Ísọ̀;+ mo sọ àwọn òkè rẹ̀ di ahoro,+ màá jẹ́ kí àwọn ajáko inú aginjù gba ogún rẹ̀.”+