23 Jèhófà sì sọ fún un pé: “Orílẹ̀-èdè méjì ló wà nínú ikùn+ rẹ, èèyàn méjì tó yàtọ̀ síra máa tinú rẹ+ jáde; orílẹ̀-èdè kan máa lágbára ju ìkejì+ lọ, ẹ̀gbọ́n sì máa sin àbúrò.”+
26 Lẹ́yìn náà, àbúrò rẹ̀ jáde, ó sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú, torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.*+ Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Ísákì nígbà tí Rèbékà bí àwọn ọmọ náà.
29 Kí àwọn èèyàn máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹrí ba fún ọ. Kí o di ọ̀gá lórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ọmọ ìyá rẹ sì máa tẹrí ba fún ọ.+ Kí ègún wà lórí ẹnikẹ́ni tó bá gégùn-ún fún ọ, kí ìbùkún sì wà lórí ẹnikẹ́ni tó bá ń súre fún ọ.”+
37 Àmọ́ Ísákì dá Ísọ̀ lóhùn pé: “Mo ti fi ṣe olórí rẹ,+ mo ti fi gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, mo sì ti fi ọkà àti wáìnì tuntun bù kún un.+ Kí ló wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”