11 ‘Ní ọjọ́ yẹn, màá gbé àtíbàbà Dáfídì+ tó ti wó dìde,
Màá sì tún àwọn àlàfo rẹ̀ ṣe,
Màá tún àwókù rẹ̀ kọ́;
Màá tún un kọ́, á sì rí bíi ti tẹ́lẹ̀,+
12 Kí wọ́n lè gba ohun tó ṣẹ́ kù nínú Édómù,+
Àti ohun tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a fi orúkọ mi pè,’ ni Jèhófà, ẹni tó ń ṣe nǹkan yìí wí.