31 Ọlọ́run gbé ẹni yìí ga sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ láti jẹ́ Olórí Aṣojú+ àti Olùgbàlà,+ kí ó lè mú kí Ísírẹ́lì ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+
10 Torí ó yẹ kí ẹni tí ohun gbogbo torí rẹ̀ wà, tí ohun gbogbo sì tipasẹ̀ rẹ̀ wà, bí o ti ń mú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo,+ sọ Olórí Aṣojú ìgbàlà+ wọn di pípé nípasẹ̀ ìjìyà.+