10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+ 11 Èṣù wá fi í sílẹ̀,+ sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún un.+