2 àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́+ wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin èèyàn rẹwà. Wọ́n sì ń fi gbogbo ẹni tó wù wọ́n ṣe aya. 3 Jèhófà wá sọ pé: “Ẹ̀mí mi ò ní gba èèyàn láyè títí láé,+ torí ẹlẹ́ran ara ni. Torí náà, ọgọ́fà (120) ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”+