2 Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí* máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà,+ kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí+ ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.
11 Nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ti hàn kedere, kí onírúurú èèyàn lè rí ìgbàlà.+12 Èyí ń kọ́ wa pé ká kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé sílẹ̀,+ ká sì máa fi àròjinlẹ̀, òdodo àti ìfọkànsìn Ọlọ́run gbé nínú ètò àwọn nǹkan yìí,*+