3 ó sọ pé: “Ẹ má ṣe pa ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí a fi máa gbé èdìdì lé+ iwájú orí+ àwọn ẹrú Ọlọ́run wa.”
4 Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a gbé èdìdì lé, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000), a gbé èdìdì lé wọn látinú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:+