10 àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) náà+ á wólẹ̀ níwájú Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n á jọ́sìn Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé, wọ́n á sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n á sọ pé:
8 Nígbà tó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún + (24) náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti abọ́ wúrà tí tùràrí kún inú rẹ̀. (Tùràrí náà túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.)+
4 Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà + wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n sọ pé: “Àmín! Ẹ yin Jáà!”*+