10 Mo fẹ́ mọ Kristi àti agbára àjíǹde rẹ̀,+ kí n jẹ irú ìyà tó jẹ,+ kí n sì kú irú ikú tó kú,+11 kí n lè rí i bóyá lọ́nàkọnà, ọwọ́ mi á tẹ àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò nínú ikú.+
16 nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú áńgẹ́lì+ àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tó ti kú nínú Kristi ló sì máa kọ́kọ́ dìde.+