22 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tí kò bá yéé bínú+ sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún ilé ẹjọ́; ẹnikẹ́ni tó bá sì sọ̀rọ̀ àbùkù tí kò ṣeé gbọ́ sétí sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé, ‘Ìwọ òpònú aláìníláárí!’ Gẹ̀hẹ́nà* oníná ló máa tọ́ sí i.+
9 Bákan náà, tí ojú rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní olójú kan ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà* oníná+ pẹ̀lú ojú méjèèjì.
8 Àmọ́ ní ti àwọn ojo àti àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́+ àti àwọn tí èérí wọn ń ríni lára àti àwọn apààyàn+ àti àwọn oníṣekúṣe*+ àti àwọn tó ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo òpùrọ́,+ ìpín wọn máa wà nínú adágún tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì.”+