ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

      • Wọ́n bá àwọn ọmọ Éfúrémù jà (1-7)

        • Wọ́n ní kí wọ́n pe Ṣíbólẹ́tì (6)

      • Íbísánì, Élónì àti Ábídónì di onídàájọ́ (8-15)

Àwọn Onídàájọ́ 12:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “wọ́n sọdá sí apá àríwá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 8:1

Àwọn Onídàájọ́ 12:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mo fi ọkàn mi sọ́wọ́ mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 11:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2007, ojú ìwé 10

Àwọn Onídàájọ́ 12:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 3:12, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2007, ojú ìwé 10

Àwọn Onídàájọ́ 12:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:28; 7:24

Àwọn Onídàájọ́ 12:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2007, ojú ìwé 10

Àwọn Onídàájọ́ 12:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:16

Àwọn Onídàájọ́ 12:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:12; Ẹk 17:16; Nọ 13:29; 1Sa 15:2

Àwọn míì

Oníd. 12:1Ond 8:1
Oníd. 12:3Ond 11:29
Oníd. 12:4Di 3:12, 13
Oníd. 12:5Ond 3:28; 7:24
Oníd. 12:8Ond 2:16
Oníd. 12:15Jẹ 36:12; Ẹk 17:16; Nọ 13:29; 1Sa 15:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Onídàájọ́ 12:1-15

Àwọn Onídàájọ́

12 Wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn ọkùnrin Éfúrémù, wọ́n sì sọdá sí Sáfónì,* wọ́n wá sọ fún Jẹ́fútà pé: “Kí ló dé tí o ò pè wá pé ká bá ọ lọ nígbà tí o sọdá lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà?+ A máa dáná sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.” 2 Àmọ́ Jẹ́fútà sọ fún wọn pé: “Èmi àtàwọn èèyàn mi bá àwọn ọmọ Ámónì jà gidigidi. Mo pè yín pé kí ẹ wá ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ẹ ò gbà mí lọ́wọ́ wọn. 3 Nígbà tí mo rí i pé ẹ ò wá gbà mí sílẹ̀, mo pinnu pé màá fi ẹ̀mí ara mi wewu,* mo lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà,+ Jèhófà sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́. Kí ló wá dé tí ẹ fi wá bá mi jà lónìí?”

4 Ni Jẹ́fútà bá kó gbogbo àwọn ọkùnrin Gílíádì+ jọ, wọ́n sì bá Éfúrémù jà; àwọn ọkùnrin Gílíádì ṣẹ́gun àwọn Éfúrémù tí wọ́n sọ pé: “Ìsáǹsá lásánlàsàn láti Éfúrémù ni yín, ẹ̀yin ọmọ Gílíádì tí ẹ wà láàárín Éfúrémù àti Mánásè.” 5 Gílíádì wá gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò Jọ́dánì+ mọ́ Éfúrémù lọ́wọ́; nígbà tí àwọn ọkùnrin Éfúrémù sì ń wá bí wọ́n á ṣe sá lọ, wọ́n á sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí n sọdá”; àwọn ọkùnrin Gílíádì á wá bi wọ́n níkọ̀ọ̀kan pé: “Ṣé ọmọ Éfúrémù ni ọ́?” Tó bá fèsì pé, “Rárá!” 6 wọ́n á ní: “Jọ̀ọ́ sọ pé Ṣíbólẹ́tì.” Àmọ́ ó máa sọ pé: “Síbólẹ́tì,” torí kò lè pe ọ̀rọ̀ yẹn dáadáa. Wọ́n á wá mú un, wọ́n á sì pa á níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú Jọ́dánì. Bí wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rún méjì (42,000) àwọn Éfúrémù nígbà yẹn nìyẹn.

7 Ọdún mẹ́fà ni Jẹ́fútà fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, Jẹ́fútà ọmọ Gílíádì kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú rẹ̀ ní Gílíádì.

8 Íbísánì láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù di onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn rẹ̀.+ 9 Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n (30) ọmọbìnrin. Ó ní kí àwọn ọmọbìnrin òun lọ fẹ́ àwọn ọkùnrin tí kì í ṣe ara agbo ilé òun, ó sì mú ọgbọ̀n (30) obìnrin wá pé kí wọ́n di ìyàwó àwọn ọmọkùnrin òun. Ọdún méje ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 10 Lẹ́yìn náà, Íbísánì kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

11 Lẹ́yìn rẹ̀, Élónì ọmọ Sébúlúnì di onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì; ọdún mẹ́wàá ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 12 Élónì ọmọ Sébúlúnì kú, wọ́n sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Sébúlúnì.

13 Lẹ́yìn rẹ̀, Ábídónì ọmọ Hílẹ́lì ará Pírátónì di onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 14 Ó ní ogójì (40) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n (30) ọmọ ọmọ tí wọ́n ń gun àádọ́rin (70) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ọdún mẹ́jọ ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 15 Ábídónì ọmọ Hílẹ́lì ará Pírátónì kú, wọ́n sì sin ín sí Pírátónì ní ilẹ̀ Éfúrémù ní òkè ọmọ Ámálékì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́