ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Móábù ń bá a lọ (1-14)

Àìsáyà 16:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:19
  • +Nọ 21:13

Àìsáyà 16:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:8, 42

Àìsáyà 16:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:16, 17
  • +Sm 45:6; 72:1, 2; Ais 9:6, 7; 32:1; Jer 23:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 194-195

Àìsáyà 16:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:26, 29; Sef 2:9, 10
  • +Emọ 2:1

Àìsáyà 16:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 15:2; Jer 48:20
  • +2Ọb 3:24, 25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 193

Àìsáyà 16:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí èso àjàrà pupa kún ara rẹ̀ fọ́fọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:15, 17
  • +Nọ 32:37, 38; Joṣ 13:15, 19
  • +Joṣ 13:24, 25; Jer 48:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 193

Àìsáyà 16:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́ “Torí pé wọ́n ti ń kígbe ogun sórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 15:4; Jer 48:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 193

Àìsáyà 16:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:33
  • +Sef 2:9

Àìsáyà 16:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 15:5; Jer 48:36
  • +Ais 15:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 193

Àìsáyà 16:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:7, 35

Àìsáyà 16:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí wọ́n fara balẹ̀ kà bíi ti alágbàṣe”; ìyẹn, ní ọdún mẹ́ta géérégé.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 25:10; Jer 48:46, 47; Sef 2:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 193-194

Àwọn míì

Àìsá. 16:2Jer 48:19
Àìsá. 16:2Nọ 21:13
Àìsá. 16:4Jer 48:8, 42
Àìsá. 16:52Sa 7:16, 17
Àìsá. 16:5Sm 45:6; 72:1, 2; Ais 9:6, 7; 32:1; Jer 23:5
Àìsá. 16:6Jer 48:26, 29; Sef 2:9, 10
Àìsá. 16:6Emọ 2:1
Àìsá. 16:7Ais 15:2; Jer 48:20
Àìsá. 16:72Ọb 3:24, 25
Àìsá. 16:8Joṣ 13:15, 17
Àìsá. 16:8Nọ 32:37, 38; Joṣ 13:15, 19
Àìsá. 16:8Joṣ 13:24, 25; Jer 48:32
Àìsá. 16:9Ais 15:4; Jer 48:34
Àìsá. 16:10Jer 48:33
Àìsá. 16:10Sef 2:9
Àìsá. 16:11Ais 15:5; Jer 48:36
Àìsá. 16:11Ais 15:1
Àìsá. 16:12Jer 48:7, 35
Àìsá. 16:14Ais 25:10; Jer 48:46, 47; Sef 2:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 16:1-14

Àìsáyà

16 Ẹ fi àgbò ránṣẹ́ sí alákòóso ilẹ̀ náà,

Láti Sẹ́ẹ́là gba aginjù

Lọ sórí òkè ọmọbìnrin Síónì.

 2 Bí ẹyẹ tí wọ́n lé kúrò nínú ìtẹ́ rẹ̀ +

Ni àwọn ọmọbìnrin Móábù máa rí níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò Áánónì.+

 3 “Ẹ gbani nímọ̀ràn, ẹ tẹ̀ lé ìpinnu náà.

Jẹ́ kí òjìji rẹ ní ọ̀sán gangan dà bí òru.

Fi àwọn tí wọ́n fọ́n ká pa mọ́, má sì dalẹ̀ àwọn tó ń sá lọ.

 4 Kí àwọn èèyàn mi tó fọ́n ká máa gbé inú rẹ, ìwọ Móábù.

Di ibi ààbò fún wọn torí ẹni tó ń pani run.+

Òpin máa dé bá aninilára,

Ìparun náà máa dópin,

Àwọn tó ń tẹ ẹlòmíì mọ́lẹ̀ sì máa pa rẹ́ ní ayé.

 5 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa wá mú kí ìtẹ́ kan fìdí múlẹ̀ gbọn-in.

Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ nínú àgọ́ Dáfídì máa jẹ́ olóòótọ́;+

Ó máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì máa yára ṣe òdodo.”+

 6 A ti gbọ́ bí Móábù ṣe ń gbéra ga, ó ń gbéra ga gan-an;+

Bó ṣe ń gbéra ga, tó ń yangàn, tó sì ń bínú;+

Àmọ́ pàbó ni ọ̀rọ̀ asán rẹ̀ máa já sí.

 7 Torí náà, Móábù máa pohùn réré ẹkún torí Móábù;

Gbogbo wọn máa pohùn réré ẹkún.+

Àwọn tí wọ́n lù máa dárò torí ìṣù àjàrà gbígbẹ ti Kiri-hárésétì.+

 8 Torí àwọn ilẹ̀ onípele Hẹ́ṣíbónì+ ti gbẹ,

Àjàrà Síbúmà,+

Àwọn alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè ti tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó pupa fòò* mọ́lẹ̀;

Wọ́n ti lọ títí dé Jásérì;+

Wọ́n ti tàn dé aginjù.

Àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ ti tàn kálẹ̀, wọ́n sì ti lọ títí dé òkun.

 9 Ìdí nìyẹn tí màá fi sunkún torí àjàrà Síbúmà bí mo ṣe ń sunkún torí Jásérì.

Màá fi omijé mi rin ọ́ gbingbin, ìwọ Hẹ́ṣíbónì àti Éléálè,+

Torí pé igbe tí wọ́n ń ké torí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ ti dópin.*

10 A ti mú ayọ̀ àti ìdùnnú kúrò nínú ọgbà eléso,

Kò sì sí orin ayọ̀ tàbí ariwo nínú àwọn ọgbà àjàrà.+

Ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ àjàrà kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ ní àwọn ibi ìfúntí láti ṣe wáìnì,

Torí mo ti mú kí ariwo náà dáwọ́ dúró.+

11 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú mi lọ́hùn-ún ń ru sókè torí Móábù,+

Bí ìgbà tí wọ́n ń ta háàpù,

Àti inú mi lọ́hùn-ún torí Kiri-hárésétì.+

12 Kódà, tí Móábù bá tán ara rẹ̀ lókun lórí ibi gíga, tó sì lọ gbàdúrà nínú ibi mímọ́ rẹ̀, kò ní rí nǹkan kan ṣe.+

13 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti sọ nípa Móábù nìyí. 14 Ní báyìí, Jèhófà sọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́ta, bí iye ọdún alágbàṣe,* onírúurú rúkèrúdò ni wọ́n máa fi dójú ti ògo Móábù, àwọn tó máa ṣẹ́ kù máa kéré gan-an, wọn ò sì ní já mọ́ nǹkan kan.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́