ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Ó kéde ìyọnu kẹwàá (1-10)

        • Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè ẹ̀bùn (2)

Ẹ́kísódù 11:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:34
  • +Ẹk 12:31, 32

Ẹ́kísódù 11:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:21, 22; 12:35, 36; Sm 105:37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 26

Ẹ́kísódù 11:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:29

Ẹ́kísódù 11:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:22, 23; Sm 78:51; 105:36; 136:10; Heb 11:28
  • +Ẹk 12:12

Ẹ́kísódù 11:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:30

Ẹ́kísódù 11:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “yọ ahọ́n sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 8:22; 9:3, 4; 10:23; 12:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2020, ojú ìwé 4

Ẹ́kísódù 11:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:33

Ẹ́kísódù 11:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:19; 7:4; Ro 9:17, 18
  • +Ẹk 7:3

Ẹ́kísódù 11:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 135:9
  • +Ẹk 4:21; 9:15, 16; 10:20

Àwọn míì

Ẹ́kís. 11:1Di 4:34
Ẹ́kís. 11:1Ẹk 12:31, 32
Ẹ́kís. 11:2Ẹk 3:21, 22; 12:35, 36; Sm 105:37
Ẹ́kís. 11:4Ẹk 12:29
Ẹ́kís. 11:5Ẹk 4:22, 23; Sm 78:51; 105:36; 136:10; Heb 11:28
Ẹ́kís. 11:5Ẹk 12:12
Ẹ́kís. 11:6Ẹk 12:30
Ẹ́kís. 11:7Ẹk 8:22; 9:3, 4; 10:23; 12:13
Ẹ́kís. 11:8Ẹk 12:33
Ẹ́kís. 11:9Ẹk 3:19; 7:4; Ro 9:17, 18
Ẹ́kís. 11:9Ẹk 7:3
Ẹ́kís. 11:10Sm 135:9
Ẹ́kís. 11:10Ẹk 4:21; 9:15, 16; 10:20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 11:1-10

Ẹ́kísódù

11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ó ku ìyọnu kan tí màá mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó máa jẹ́ kí ẹ kúrò níbí.+ Ṣe ló máa lé yín kúrò níbí nígbà tó bá gbà pé kí ẹ máa lọ.+ 2 Torí náà, sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin béèrè àwọn nǹkan tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe lọ́wọ́ ọmọnìkejì wọn.”+ 3 Jèhófà sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà rí ojúure àwọn ará Íjíbítì. Mósè fúnra rẹ̀ ti wá di ẹni ńlá nílẹ̀ Íjíbítì lójú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àti àwọn èèyàn náà.

4 Mósè wá sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀gànjọ́ òru, màá lọ sí àárín Íjíbítì,+ 5 gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì yóò sì kú,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹrúbìnrin tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn.+ 6 Igbe ẹkún máa pọ̀ gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, irú ẹ̀ ò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 7 Àmọ́, ajá ò tiẹ̀ ní gbó* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àti ẹran ọ̀sìn wọn, kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà lè fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’+ 8 Ó dájú pé gbogbo ìránṣẹ́ rẹ yóò wá bá mi, wọ́n á wólẹ̀ fún mi, wọ́n á sì sọ pé, ‘Máa lọ, ìwọ àti gbogbo èèyàn tó ń tẹ̀ lé ọ.’+ Lẹ́yìn náà, èmi yóò lọ.” Ló bá fi ìbínú kúrò níwájú Fáráò.

9 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fáráò ò ní fetí sí yín,+ kí iṣẹ́ ìyanu mi lè pọ̀ sí i nílẹ̀ Íjíbítì.”+ 10 Mósè àti Áárónì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí níwájú Fáráò,+ àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́