ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Tẹsalóníkà 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Tẹsalóníkà

      • Ìkíni (1, 2)

      • Ìgbàgbọ́ àwọn ará Tẹsalóníkà ń lágbára sí i (3-5)

      • Ẹ̀san lórí àwọn aláìgbọràn (6-10)

      • Àdúrà fún ìjọ (11, 12)

2 Tẹsalóníkà 1:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 1:19

2 Tẹsalóníkà 1:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 3:12; 4:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2005, ojú ìwé 32

2 Tẹsalóníkà 1:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ìpọ́njú.”

  • *

    Tàbí “fara dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 2:19
  • +1Tẹ 1:6; 2:14; 1Pe 2:21

2 Tẹsalóníkà 1:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 14:22; Ro 8:17; 2Ti 2:12

2 Tẹsalóníkà 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 12:19; Ifi 6:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 33

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 19

2 Tẹsalóníkà 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 17:29, 30; 1Pe 1:7
  • +Mk 8:38

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 19

    5/1/1993, ojú ìwé 22

2 Tẹsalóníkà 1:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 2:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 33

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2019, ojú ìwé 12-13

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 19

    5/1/1993, ojú ìwé 22

2 Tẹsalóníkà 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Pe 3:7

2 Tẹsalóníkà 1:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:30

Àwọn míì

2 Tẹs. 1:12Kọ 1:19
2 Tẹs. 1:31Tẹ 3:12; 4:9, 10
2 Tẹs. 1:41Tẹ 2:19
2 Tẹs. 1:41Tẹ 1:6; 2:14; 1Pe 2:21
2 Tẹs. 1:5Iṣe 14:22; Ro 8:17; 2Ti 2:12
2 Tẹs. 1:6Ro 12:19; Ifi 6:9, 10
2 Tẹs. 1:7Lk 17:29, 30; 1Pe 1:7
2 Tẹs. 1:7Mk 8:38
2 Tẹs. 1:8Ro 2:8
2 Tẹs. 1:92Pe 3:7
2 Tẹs. 1:11Ro 8:30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Tẹsalóníkà 1:1-12

Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà

1 Pọ́ọ̀lù, Sílífánù* àti Tímótì,+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa:

2 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Olúwa.

3 Ẹ̀yin ará, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín. Ó yẹ bẹ́ẹ̀, torí pé ìgbàgbọ́ yín ń lágbára sí i, ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i.+ 4 Nítorí èyí, à ń fi yín yangàn+ láàárín ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro* tí ẹ̀ ń dojú kọ.*+ 5 Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, tó ń mú kí a kà yín yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run tí ẹ̀ ń torí rẹ̀ jìyà.+

6 Èyí jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run kà á sí òdodo láti san ìpọ́njú pa dà fún àwọn tó ń pọ́n yín lójú.+ 7 Àmọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ní ìpọ́njú máa rí ìtura gbà pẹ̀lú wa nígbà ìfihàn Jésù Olúwa+ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára+ 8 nínú iná tó ń jó fòfò, bó ṣe ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.+ 9 Àwọn yìí máa fara gbá ìyà ìdájọ́ ìparun ayérayé+ láti iwájú Olúwa àti látinú ògo agbára rẹ̀, 10 nígbà tó bá dé kí a lè yìn ín lógo pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́ sì lè wò ó ní ọjọ́ yẹn tìyanutìyanu, nítorí ẹ gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún yín gbọ́.

11 Torí bẹ́ẹ̀, à ń gbàdúrà fún yín nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run wa kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀,+ kó sì fi agbára rẹ̀ ṣe gbogbo ohun rere tó wù ú láṣepé pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́. 12 Kí a lè yin orúkọ Olúwa wa Jésù lógo nínú yín, kí a sì yin ẹ̀yin náà lógo nínú rẹ̀, nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa àti ti Jésù Kristi Olúwa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́