ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Bí wọ́n ṣe máa dó ti Jerúsálẹ́mù (1-17)

        • Ó ru ẹ̀bi fún 390 ọjọ́ àti 40 ọjọ́ (4-7)

Ìsíkíẹ́lì 4:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 63

Ìsíkíẹ́lì 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:11; Jer 39:1
  • +2Ọb 25:1
  • +Jer 6:6; 32:24
  • +Isk 21:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 63

Ìsíkíẹ́lì 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 12:6; 24:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 63

Ìsíkíẹ́lì 4:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rù ú,” ìyẹn, kí Ìsíkíẹ́lì fi ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ rù ú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:21

Ìsíkíẹ́lì 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:34; 1Ọb 12:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 67-68

Ìsíkíẹ́lì 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 32

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 67-68

Ìsíkíẹ́lì 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 52:4

Ìsíkíẹ́lì 4:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 4:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 63

Ìsíkíẹ́lì 4:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Nǹkan bíi 230 gíráàmù. Wo Àfikún B14.

Ìsíkíẹ́lì 4:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Nǹkan bíi Lítà 0.6. Wo Àfikún B14.

Ìsíkíẹ́lì 4:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 9:3

Ìsíkíẹ́lì 4:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí “èèwọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:31; Le 7:24; 11:40
  • +Di 14:3; Ais 65:4; 66:17

Ìsíkíẹ́lì 4:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    8/1/1994, ojú ìwé 13

Ìsíkíẹ́lì 4:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:26; Ais 3:1; Isk 5:16
  • +2Ọb 25:3; Jer 37:21; Ida 1:11; 4:9; 5:9, 10
  • +Isk 12:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 63

Àwọn míì

Ìsík. 4:22Ọb 24:11; Jer 39:1
Ìsík. 4:22Ọb 25:1
Ìsík. 4:2Jer 6:6; 32:24
Ìsík. 4:2Isk 21:22
Ìsík. 4:3Isk 12:6; 24:24
Ìsík. 4:42Ọb 17:21
Ìsík. 4:5Nọ 14:34; 1Ọb 12:19, 20
Ìsík. 4:62Ọb 23:27
Ìsík. 4:7Jer 52:4
Ìsík. 4:9Isk 4:5
Ìsík. 4:13Ho 9:3
Ìsík. 4:14Ẹk 22:31; Le 7:24; 11:40
Ìsík. 4:14Di 14:3; Ais 65:4; 66:17
Ìsík. 4:16Le 26:26; Ais 3:1; Isk 5:16
Ìsík. 4:162Ọb 25:3; Jer 37:21; Ida 1:11; 4:9; 5:9, 10
Ìsík. 4:16Isk 12:18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 4:1-17

Ìsíkíẹ́lì

4 “Ìwọ ọmọ èèyàn, gbé bíríkì kan, kí o sì gbé e síwájú rẹ. Ya àwòrán Jerúsálẹ́mù sórí rẹ̀. 2 Dó tì í,+ fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká,+ mọ òkìtì láti dó tì í,+ pàgọ́ yí i ká, kí o sì gbé àwọn igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri+ yí i ká. 3 Gbé agbada onírin, kí o sì fi ṣe ògiri onírin láàárín ìwọ àti ìlú náà. Kí o wá dojú kọ ọ́, kí a sì dó tì í; ìwọ ni kí o dó tì í. Àmì ni èyí jẹ́ fún ilé Ísírẹ́lì.+

4 “Kí o wá fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì ru ara rẹ.*+ Iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀ ni wàá fi ru ẹ̀bi wọn. 5 Èmi yóò sì mú kí o fi irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́ ru ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì,+ èyí tó dọ́gba pẹ̀lú iye ọdún tí wọ́n fi jẹ̀bi. 6 O sì gbọ́dọ̀ lo ọjọ́ náà pé.

“Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìwọ yóò fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún dùbúlẹ̀, ìwọ yóò sì di ẹ̀bi ilé Júdà+ ru ara rẹ fún ogójì (40) ọjọ́. Ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan ni mo là kalẹ̀ fún ọ. 7 Ìwọ yóò sì yíjú sí Jerúsálẹ́mù láti dó tì í,+ láìfi aṣọ bo apá rẹ, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀.

8 “Wò ó! èmi yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa yí ẹ̀gbẹ́ rẹ pa dà, títí ìwọ yóò fi parí ọjọ́ tí wàá fi dó tì í.

9 “Kí o sì mú àlìkámà,* ọkà bálì, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, jéró àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì, kí o kó wọn sínú ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe búrẹ́dì tí wàá jẹ. Iye ọjọ́ tí o fi ẹ̀gbẹ́ rẹ dùbúlẹ̀ ni wàá fi jẹ ẹ́, ìyẹn irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́.+ 10 Ìwọ yóò wọn oúnjẹ tí ó tó ogún (20) ṣékélì,* òun sì ni wàá máa jẹ lójúmọ́. Ó ní àkókò tí wàá máa jẹ ẹ́.

11 “Ṣe ni wàá máa wọn omi tí o fẹ́ mu, ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n hínì* lo máa wọ̀n. Tí àkókò bá tó ni wàá mu ún.

12 “O máa jẹ ẹ́ bí ìgbà tí ò ń jẹ búrẹ́dì ribiti tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe; ojú wọn lo ti máa ṣe é, wàá sì fi ìgbẹ́ èèyàn dá iná rẹ̀, èyí tó ti gbẹ.” 13 Jèhófà wá sọ pé: “Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí nìyẹn, oúnjẹ àìmọ́ ni wọ́n máa jẹ.”+

14 Ní mo bá sọ pé: “Rárá o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Láti kékeré títí di báyìí, mi* ò jẹ òkú ẹran rí tàbí ẹran tí wọ́n fà ya+ tó máa sọ mí di aláìmọ́, mi ò sì jẹ ẹran kankan tó jẹ́ aláìmọ́* rí.”+

15 Ó sọ fún mi pé: “Ó dáa, màá jẹ́ kí o lo ìgbẹ́ màlúù dípò ti èèyàn, òun lo sì máa fi dá iná tí wàá fi ṣe búrẹ́dì.” 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà* ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+ 17 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí ẹnu yà wọ́n, bí wọ́n ṣe ń wo ara wọn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn á sì mú kí wọ́n ṣègbé torí pé wọn ò ní búrẹ́dì àti omi tí ó tó.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́