ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Ọ̀tẹ̀ àti rìkíṣí tí Ábúsálómù dì (1-12)

      • Dáfídì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù (13-30)

      • Áhítófẹ́lì dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù (31)

      • Ọba rán Húṣáì láti ta ko Áhítófẹ́lì (32-37)

2 Sámúẹ́lì 15:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 8:11; 1Ọb 1:5; Owe 11:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2022,

2 Sámúẹ́lì 15:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 25:7; Rut 4:1
  • +1Sa 8:20; 2Sa 8:15

2 Sámúẹ́lì 15:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 10:9; 55:21; Owe 26:25

2 Sámúẹ́lì 15:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jí ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 11:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2012, ojú ìwé 13

2 Sámúẹ́lì 15:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “40 ọdún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 3:2

2 Sámúẹ́lì 15:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “jọ́sìn.” Ní Héb., “ṣe iṣẹ́ ìsìn fún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:21
  • +2Sa 13:38; 14:23

2 Sámúẹ́lì 15:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 2:1; 5:1, 5; 1Kr 3:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2022,

2 Sámúẹ́lì 15:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “olùdámọ̀ràn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 16:23; 17:14; 23:8, 34
  • +Sm 41:9; 55:12, 13; Jo 13:18
  • +Joṣ 15:20, 51
  • +Sm 3:1; Owe 24:21

2 Sámúẹ́lì 15:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 19:9; Sm 3:àkọlé
  • +2Sa 12:11

2 Sámúẹ́lì 15:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 18:24

2 Sámúẹ́lì 15:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:11; 16:21; 20:3

2 Sámúẹ́lì 15:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2009, ojú ìwé 27

2 Sámúẹ́lì 15:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí wọ́n ń sọdá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “sì ń sọdá níwájú ọba.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:18; 20:7; 1Ọb 1:38; 1Kr 18:17
  • +Joṣ 13:2, 3
  • +1Sa 27:4; 1Kr 18:1

2 Sámúẹ́lì 15:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2009, ojú ìwé 27

2 Sámúẹ́lì 15:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 2:5, 6; Sm 25:10; 57:3; 61:7; 89:14

2 Sámúẹ́lì 15:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 17:17; 18:24

2 Sámúẹ́lì 15:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:2

2 Sámúẹ́lì 15:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:36, 37; 2Kr 30:14; Jo 18:1

2 Sámúẹ́lì 15:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:17; 20:25; 1Ọb 1:8; 2:35; 1Kr 6:8
  • +Nọ 8:19
  • +Ẹk 37:1; Le 16:2
  • +Nọ 4:15; 7:9; 1Kr 15:2
  • +1Sa 22:20; 30:7

2 Sámúẹ́lì 15:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 6:17
  • +2Sa 7:2; Sm 26:8; 27:4

2 Sámúẹ́lì 15:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 9:9
  • +2Sa 17:17

2 Sámúẹ́lì 15:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:36; 17:16, 21

2 Sámúẹ́lì 15:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 21:1; 24:3; Iṣe 1:12

2 Sámúẹ́lì 15:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àmọ̀ràn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 41:9; 55:12, 13; Jo 13:18
  • +Sm 3:àkọlé
  • +Sm 3:7
  • +2Sa 16:23; 17:14

2 Sámúẹ́lì 15:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 16:16
  • +Joṣ 16:1, 2

2 Sámúẹ́lì 15:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 16:18, 19
  • +2Sa 17:7, 14

2 Sámúẹ́lì 15:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 17:15, 16

2 Sámúẹ́lì 15:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:19
  • +2Sa 17:17; 1Ọb 1:42

2 Sámúẹ́lì 15:37

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rẹ́ àfinúhàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 16:16; 1Kr 27:33

Àwọn míì

2 Sám. 15:11Sa 8:11; 1Ọb 1:5; Owe 11:2
2 Sám. 15:2Di 25:7; Rut 4:1
2 Sám. 15:21Sa 8:20; 2Sa 8:15
2 Sám. 15:5Sm 10:9; 55:21; Owe 26:25
2 Sám. 15:6Owe 11:9
2 Sám. 15:72Sa 3:2
2 Sám. 15:8Le 22:21
2 Sám. 15:82Sa 13:38; 14:23
2 Sám. 15:102Sa 2:1; 5:1, 5; 1Kr 3:4
2 Sám. 15:122Sa 16:23; 17:14; 23:8, 34
2 Sám. 15:12Sm 41:9; 55:12, 13; Jo 13:18
2 Sám. 15:12Joṣ 15:20, 51
2 Sám. 15:12Sm 3:1; Owe 24:21
2 Sám. 15:142Sa 19:9; Sm 3:àkọlé
2 Sám. 15:142Sa 12:11
2 Sám. 15:15Owe 18:24
2 Sám. 15:162Sa 12:11; 16:21; 20:3
2 Sám. 15:182Sa 8:18; 20:7; 1Ọb 1:38; 1Kr 18:17
2 Sám. 15:18Joṣ 13:2, 3
2 Sám. 15:181Sa 27:4; 1Kr 18:1
2 Sám. 15:192Sa 18:2
2 Sám. 15:202Sa 2:5, 6; Sm 25:10; 57:3; 61:7; 89:14
2 Sám. 15:21Owe 17:17; 18:24
2 Sám. 15:222Sa 18:2
2 Sám. 15:231Ọb 2:36, 37; 2Kr 30:14; Jo 18:1
2 Sám. 15:242Sa 8:17; 20:25; 1Ọb 1:8; 2:35; 1Kr 6:8
2 Sám. 15:24Nọ 8:19
2 Sám. 15:24Ẹk 37:1; Le 16:2
2 Sám. 15:24Nọ 4:15; 7:9; 1Kr 15:2
2 Sám. 15:241Sa 22:20; 30:7
2 Sám. 15:252Sa 6:17
2 Sám. 15:252Sa 7:2; Sm 26:8; 27:4
2 Sám. 15:271Sa 9:9
2 Sám. 15:272Sa 17:17
2 Sám. 15:282Sa 15:36; 17:16, 21
2 Sám. 15:30Mt 21:1; 24:3; Iṣe 1:12
2 Sám. 15:31Sm 41:9; 55:12, 13; Jo 13:18
2 Sám. 15:31Sm 3:àkọlé
2 Sám. 15:31Sm 3:7
2 Sám. 15:312Sa 16:23; 17:14
2 Sám. 15:322Sa 16:16
2 Sám. 15:32Joṣ 16:1, 2
2 Sám. 15:342Sa 16:18, 19
2 Sám. 15:342Sa 17:7, 14
2 Sám. 15:352Sa 17:15, 16
2 Sám. 15:362Sa 18:19
2 Sám. 15:362Sa 17:17; 1Ọb 1:42
2 Sám. 15:372Sa 16:16; 1Kr 27:33
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 15:1-37

Sámúẹ́lì Kejì

15 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, Ábúsálómù ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, ó kó àwọn ẹṣin jọ pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+ 2 Ábúsálómù máa ń dìde láàárọ̀ kùtù, á sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tó lọ sí ẹnubodè ìlú.+ Nígbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní ẹjọ́ tó ń gbé bọ̀ lọ́dọ̀ ọba,+ Ábúsálómù á pè é, á sì sọ pé: “Ìlú wo lo ti wá?” onítọ̀hún á sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ rẹ ti wá.” 3 Ábúsálómù á wá sọ fún un pé: “Wò ó, ẹjọ́ rẹ dára, ó sì tọ́, àmọ́ kò sí ẹnì kankan láti ọ̀dọ̀ ọba tó máa fetí sí ọ.” 4 Ábúsálómù á tún sọ pé: “Ká ní wọ́n yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni! Nígbà náà, gbogbo ẹni tó ní ẹjọ́ tàbí tó ń wá ìdájọ́ á lè wá sọ́dọ̀ mi, màá sì rí i pé mo dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́.”

5 Nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ Ábúsálómù kí ó lè tẹrí ba fún un, Ábúsálómù á na ọwọ́ rẹ̀, á gbá a mú, á sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+ 6 Ohun tí Ábúsálómù máa ń ṣe sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó gbé ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba nìyẹn; torí náà, Ábúsálómù ń dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra.*+

7 Nígbà tí ọdún mẹ́rin* parí, Ábúsálómù sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí Hébúrónì,+ kí n lè lọ san ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà. 8 Nítorí ìránṣẹ́ rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ ńlá kan+ nígbà tí mò ń gbé ní Géṣúrì+ ní Síríà pé: ‘Tí Jèhófà bá mú mi pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù, màá rúbọ sí* Jèhófà.’” 9 Torí náà, ọba sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ló bá gbéra, ó sì lọ sí Hébúrónì.

10 Ábúsálómù wá rán àwọn amí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé: “Gbàrà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ kéde pé, ‘Ábúsálómù ti di ọba ní Hébúrónì!’”+ 11 Nígbà náà, igba (200) ọkùnrin tẹ̀ lé Ábúsálómù lọ láti Jerúsálẹ́mù; ó pè wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé e láìfura, wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 12 Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí ó rú àwọn ẹbọ náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Áhítófẹ́lì+ ará Gílò, agbani-nímọ̀ràn*+ Dáfídì, láti Gílò+ ìlú rẹ̀. Ọ̀tẹ̀ náà ń gbilẹ̀ sí i, àwọn tó sì wà lẹ́yìn Ábúsálómù ń pọ̀ sí i.+

13 Nígbà tó yá, ẹnì kan wá yọ́ ọ̀rọ̀ sọ fún Dáfídì pé: “Ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti yí sọ́dọ̀ Ábúsálómù.” 14 Ní kíá, Dáfídì sọ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a sá lọ,+ nítorí kò sí ìkankan lára wa tó máa bọ́ lọ́wọ́ Ábúsálómù! Ẹ ṣe kíá, kí ó má bàa yára lé wa bá, kí ó mú àjálù bá wa, kí ó sì fi idà pa ìlú yìí!”+ 15 Àwọn ìránṣẹ́ ọba sọ fún ọba pé: “Ohunkóhun tí olúwa wa ọba bá sọ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ṣe tán láti ṣe.”+ 16 Nítorí náà, ọba jáde, gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀ lé e, àmọ́ ọba ní kí àwọn wáhàrì*+ mẹ́wàá dúró láti máa tọ́jú ilé. 17 Ọba ń bá ìrìn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn èèyàn náà ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì dúró ní Bẹti-méhákì.

18 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ kúrò* àti gbogbo àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti àwọn ará Gátì,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń kọjá bí ọba ti ń yẹ̀ wọ́n wò.* 19 Nígbà náà, ọba sọ fún Ítáì+ ará Gátì pé: “Kí ló dé tí ìwọ náà fi fẹ́ bá wa lọ? Pa dà, kí o sì lọ máa gbé pẹ̀lú ọba tuntun, nítorí àjèjì ni ọ́, ńṣe ni o sì sá kúrò ní ìlú rẹ. 20 Kò tíì pẹ́ tí o dé, ṣé kí n wá sọ pé kí o máa bá wa rìn káàkiri lónìí, láti lọ síbi tí mo bá ń lọ nígbà tí mo bá ń lọ? Pa dà, ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ, kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́+ hàn sí ọ!” 21 Ṣùgbọ́n Ítáì dá ọba lóhùn pé: “Bí Jèhófà àti olúwa mi ọba ti wà láàyè, ibikíbi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!”+ 22 Dáfídì bá sọ fún Ítáì+ pé: “Ó yá sọdá.” Nítorí náà, Ítáì ará Gátì sọdá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin àti àwọn ọmọ tó wà pẹ̀lú rẹ̀.

23 Gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń sunkún kíkankíkan nígbà tí àwọn èèyàn náà ń sọdá, ọba sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Kídírónì;+ gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sọdá sójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù. 24 Sádókù+ wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n ru àpótí+ májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́; wọ́n sì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ kalẹ̀; Ábíátárì+ náà wà níbẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn èèyàn náà sọdá láti inú ìlú náà. 25 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Sádókù pé: “Gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sínú ìlú.+ Tí Jèhófà bá ṣojú rere sí mi, á mú mi pa dà, á tún jẹ́ kí n rí i àti ibi tó máa ń wà.+ 26 Àmọ́ tí ó bá sọ pé, ‘Inú mi ò dùn sí ọ,’ nígbà náà, kí ó ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀ sí mi.” 27 Ọba wá sọ fún àlùfáà Sádókù pé: “Ṣebí aríran+ ni ọ́? Pa dà sínú ìlú ní àlàáfíà, kí o mú àwọn ọmọ yín méjèèjì dání, Áhímáásì ọmọ rẹ àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì. 28 Wò ó, màá dúró ní ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò aginjù, títí màá fi rí ẹni tí wàá ní kí ó wá jíṣẹ́ fún mi.”+ 29 Torí náà, Sádókù àti Ábíátárì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbẹ̀.

30 Bí Dáfídì ṣe ń gun Òkè* Ólífì,+ ó ń sunkún bí ó ṣe ń gòkè lọ; ó bo orí rẹ̀, ó sì ń rìn lọ láìwọ bàtà. Gbogbo àwọn èèyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà bo orí wọn, wọ́n sì ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ. 31 Dáfídì gbọ́ pé: “Áhítófẹ́lì wà lára àwọn tí ó dìtẹ̀+ pẹ̀lú Ábúsálómù.”+ Ni Dáfídì bá sọ pé: “Jèhófà,+ jọ̀wọ́ sọ ìmọ̀ràn* Áhítófẹ́lì di ti òmùgọ̀!”+

32 Nígbà tí Dáfídì dé orí òkè tí àwọn èèyàn ti máa ń forí balẹ̀ fún Ọlọ́run, Húṣáì+ ará Áríkì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀, ẹ̀wù rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. 33 Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: “Tí o bá bá mi sọdá, wàá di ẹrù sí mi lọ́rùn. 34 Àmọ́ tí o bá pa dà sínú ìlú, tí o sì sọ fún Ábúsálómù pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, Ọba. Ìránṣẹ́ bàbá rẹ ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́,’+ ìgbà náà ni wàá lè bá mi sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di asán.+ 35 Ṣebí àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ? Gbogbo ohun tí o bá gbọ́ ní ilé ọba+ ni kí o sọ fún àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì. 36 Wò ó! Àwọn ọmọ wọn méjèèjì wà pẹ̀lú wọn, Áhímáásì+ ọmọ Sádókù àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì, kí o ní kí wọ́n wá sọ gbogbo ohun tí o bá gbọ́ fún mi.” 37 Nítorí náà, Húṣáì, ọ̀rẹ́* Dáfídì,+ wá sínú ìlú bí Ábúsálómù ṣe ń wọ Jerúsálẹ́mù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́