ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sekaráyà 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

      • Ìran 6: Àkájọ ìwé tó ń fò (1-4)

      • Ìran 7: Agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà (5-11)

        • Obìnrin tó wà nínú rẹ̀ ń jẹ́ Ìwà Burúkú (8)

        • Wọ́n gbé agbọ̀n náà lọ sí ilẹ̀ Ṣínárì (9-11)

Sekaráyà 5:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ ṣẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 22

Sekaráyà 5:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:15
  • +Ẹk 20:7; Le 19:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 12/2019, ojú ìwé 1

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 22

Sekaráyà 5:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 22-24

Sekaráyà 5:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 24

Sekaráyà 5:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “eéfà,” nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí ohun ìkó-nǹkan-sí tàbí apẹ̀rẹ̀ tó dọ́gba pẹ̀lú òṣùwọ̀n eéfà. Eéfà kan jẹ́ Lítà 22. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 24

Sekaráyà 5:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 24

Sekaráyà 5:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Wọ́n sì gbé agbọ̀n náà sí àárín ayé àti ọ̀run.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 24-25

Sekaráyà 5:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Babilóníà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:8, 10; 11:1, 2; Da 1:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 24-25

Àwọn míì

Sek. 5:3Ẹk 20:15
Sek. 5:3Ẹk 20:7; Le 19:12
Sek. 5:11Jẹ 10:8, 10; 11:1, 2; Da 1:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sekaráyà 5:1-11

Sekaráyà

5 Mo tún wòkè, mo sì rí àkájọ ìwé kan tó ń fò. 2 Ó bi mí pé: “Kí lo rí?”

Mo fèsì pé: “Mo rí àkájọ ìwé tó ń fò, tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́,* tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”

3 Ó wá sọ fún mi pé: “Èyí ni ègún tó ń lọ sí gbogbo ayé, bí wọ́n ṣe kọ ọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan ìwé náà, torí gbogbo ẹni tó ń jalè+ ti lọ láìjìyà; bí wọ́n sì ṣe kọ ọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kejì, torí gbogbo ẹni tó ń búra+ ti lọ láìjìyà. 4 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Mo ti rán an jáde, yóò sì wọnú ilé olè àti ilé ẹni tó ń fi orúkọ mi búra èké; yóò wà nínú ilé náà, yóò sì jẹ ẹ́ run, pẹ̀lú àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta rẹ̀.’”

5 Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ wá síwájú, ó sì sọ fún mi pé: “Jọ̀ọ́ wòkè, kí o sì wo ohun tó ń jáde lọ.”

6 Mo wá bi í pé: “Kí ni?”

Ó fèsì pé: “Agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà* ló ń jáde lọ.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí wọ́n ṣe rí ní gbogbo ayé nìyẹn.” 7 Mo sì rí i tí wọ́n ṣí ìdérí roboto tí wọ́n fi òjé ṣe, obìnrin kan sì wà nínú agbọ̀n náà tó jókòó. 8 Áńgẹ́lì náà wá sọ pé: “Ìwà Burúkú nìyí.” Ó tì í pa dà sínú agbọ̀n náà, ó sì fi ìdérí tí wọ́n fi òjé ṣe náà dé e.

9 Lẹ́yìn náà, mo wòkè, mo sì rí obìnrin méjì tí wọ́n ń bọ̀, tí wọ́n ń yára fò nínú afẹ́fẹ́. Ìyẹ́ wọn dà bíi ti ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n sì gbé agbọ̀n náà kúrò nílẹ̀.* 10 Mo wá bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Ibo ni wọ́n ń gbé agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà yẹn lọ?”

11 Ó fèsì pé: “Ilẹ̀ Ṣínárì*+ ni wọ́n ń gbé e lọ, kí wọ́n lè kọ́lé fún obìnrin náà; tí wọ́n bá sì ti kọ́ ọ tán, wọn yóò fi í síbẹ̀, ní àyè rẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́