ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Ṣíṣákì gbógun ti Jerúsálẹ́mù (1-12)

      • Òpin ìjọba Rèhóbóámù (13-16)

2 Kíróníkà 12:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 11:17
  • +Di 32:15; 2Kr 26:11, 16

2 Kíróníkà 12:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:40; 14:25

2 Kíróníkà 12:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Na 3:9

2 Kíróníkà 12:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:22-24
  • +Di 28:15; 2Kr 15:2

2 Kíróníkà 12:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:10, 12

2 Kíróníkà 12:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:29; 2Kr 34:26, 27

2 Kíróníkà 12:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ìjọba.”

2 Kíróníkà 12:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:51
  • +1Ọb 10:16, 17; 14:25-28

2 Kíróníkà 12:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn sárésáré.”

2 Kíróníkà 12:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:10, 12
  • +Ida 3:22
  • +Jẹ 18:23-25; 1Ọb 14:1, 13; 2Kr 19:2, 3

2 Kíróníkà 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:3; 1Ọb 11:1; 14:21

2 Kíróníkà 12:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 7:3; 1Ọb 18:21; Mk 12:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2018, ojú ìwé 14-15

2 Kíróníkà 12:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:22-24
  • +2Kr 9:29; 13:22
  • +1Ọb 14:30, 31

2 Kíróníkà 12:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:9
  • +Mt 1:7

Àwọn míì

2 Kíró. 12:12Kr 11:17
2 Kíró. 12:1Di 32:15; 2Kr 26:11, 16
2 Kíró. 12:21Ọb 11:40; 14:25
2 Kíró. 12:3Na 3:9
2 Kíró. 12:51Ọb 12:22-24
2 Kíró. 12:5Di 28:15; 2Kr 15:2
2 Kíró. 12:62Kr 33:10, 12
2 Kíró. 12:71Ọb 21:29; 2Kr 34:26, 27
2 Kíró. 12:91Ọb 7:51
2 Kíró. 12:91Ọb 10:16, 17; 14:25-28
2 Kíró. 12:122Kr 33:10, 12
2 Kíró. 12:12Ida 3:22
2 Kíró. 12:12Jẹ 18:23-25; 1Ọb 14:1, 13; 2Kr 19:2, 3
2 Kíró. 12:13Di 23:3; 1Ọb 11:1; 14:21
2 Kíró. 12:141Sa 7:3; 1Ọb 18:21; Mk 12:30
2 Kíró. 12:151Ọb 12:22-24
2 Kíró. 12:152Kr 9:29; 13:22
2 Kíró. 12:151Ọb 14:30, 31
2 Kíró. 12:162Sa 5:9
2 Kíró. 12:16Mt 1:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 12:1-16

Kíróníkà Kejì

12 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ìjọba Rèhóbóámù fìdí múlẹ̀,+ tí ó sì di alágbára, ó pa Òfin Jèhófà tì,+ òun àti gbogbo Ísírẹ́lì. 2 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, nítorí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. 3 Ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba (1,200) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn agẹṣin pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí kò níye, tí wọ́n bá a wá láti Íjíbítì, ìyẹn àwọn ará Líbíà, Súkímù àti àwọn ará Etiópíà.+ 4 Ó gba àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà, níkẹyìn, ó dé Jerúsálẹ́mù.

5 Wòlíì Ṣemáyà+ wá sọ́dọ̀ Rèhóbóámù àti àwọn ìjòyè Júdà tí wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù nítorí Ṣíṣákì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹ ti fi mí sílẹ̀, èmi náà ti fi yín sílẹ̀+ sí ọwọ́ Ṣíṣákì.’” 6 Àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì àti ọba wá rẹ ara wọn sílẹ̀,+ wọ́n sì sọ pé: “Olódodo ni Jèhófà.” 7 Nígbà tí Jèhófà rí i pé wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Jèhófà bá Ṣemáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀. Mi ò ní pa wọ́n run,+ màá sì gbà wọ́n láìpẹ́. Mi ò ní tú ìbínú mi sórí Jerúsálẹ́mù látọwọ́ Ṣíṣákì. 8 Ṣùgbọ́n wọ́n á di ìránṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ nínú sísìn mí àti sísin àwọn ọba* ilẹ̀ míì.”

9 Nítorí náà, Ṣíṣákì ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà+ àti ìṣúra ilé* ọba. Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan àwọn apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 10 Nítorí náà, Ọba Rèhóbóámù ṣe àwọn apata bàbà láti fi rọ́pò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́* tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba. 11 Nígbàkigbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn ẹ̀ṣọ́ á wọlé, wọ́n á sì gbé wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n á dá wọn pa dà sí yàrá ẹ̀ṣọ́. 12 Torí pé ọba rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Jèhófà yí kúrò lórí rẹ̀,+ kò sì pa wọ́n run pátápátá.+ Yàtọ̀ síyẹn, ó rí àwọn ohun rere ní Júdà.+

13 Ọba Rèhóbóámù mú kí ipò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì ń jọba nìṣó; ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Rèhóbóámù nígbà tó di ọba, ó sì fi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Jèhófà yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ sí. Orúkọ ìyá ọba ni Náámà, ọmọ Ámónì sì ni.+ 14 Àmọ́, ọba ṣe ohun tó burú, torí pé kò pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti wá Jèhófà.+

15 Ní ti ìtàn Rèhóbóámù, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Ṣemáyà+ àti ti Ídò+ aríran tó wà nínú ìtàn ìdílé? Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+ 16 Níkẹyìn, Rèhóbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì;+ Ábíjà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́