ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 33
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jékọ́bù lọ pàdé Ísọ̀ (1-16)

      • Jékọ́bù lọ sí Ṣékémù (17-20)

Jẹ́nẹ́sísì 33:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:6
  • +Jẹ 32:22

Jẹ́nẹ́sísì 33:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:7, 12
  • +Jẹ 30:19
  • +Jẹ 30:22-24

Jẹ́nẹ́sísì 33:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:22; Sm 127:3

Jẹ́nẹ́sísì 33:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 33:2

Jẹ́nẹ́sísì 33:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:16
  • +Jẹ 32:4, 5

Jẹ́nẹ́sísì 33:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:6, 7

Jẹ́nẹ́sísì 33:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:11, 20

Jẹ́nẹ́sísì 33:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:13-15
  • +Jẹ 30:43

Jẹ́nẹ́sísì 33:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:17

Jẹ́nẹ́sísì 33:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2005, ojú ìwé 18

Jẹ́nẹ́sísì 33:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Àwọn Àtíbàbà; Ibi Ààbò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:24, 27; 1Ọb 7:46

Jẹ́nẹ́sísì 33:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:20; 28:6
  • +Joṣ 24:1
  • +Jẹ 10:19; 12:6

Jẹ́nẹ́sísì 33:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 24:32; Iṣe 7:15, 16

Jẹ́nẹ́sísì 33:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:1, 7

Àwọn míì

Jẹ́n. 33:1Jẹ 32:6
Jẹ́n. 33:1Jẹ 32:22
Jẹ́n. 33:2Jẹ 30:7, 12
Jẹ́n. 33:2Jẹ 30:19
Jẹ́n. 33:2Jẹ 30:22-24
Jẹ́n. 33:5Jẹ 32:22; Sm 127:3
Jẹ́n. 33:7Jẹ 33:2
Jẹ́n. 33:8Jẹ 32:16
Jẹ́n. 33:8Jẹ 32:4, 5
Jẹ́n. 33:9Jẹ 36:6, 7
Jẹ́n. 33:10Jẹ 32:11, 20
Jẹ́n. 33:11Jẹ 32:13-15
Jẹ́n. 33:11Jẹ 30:43
Jẹ́n. 33:13Jẹ 31:17
Jẹ́n. 33:14Jẹ 32:3
Jẹ́n. 33:17Joṣ 13:24, 27; 1Ọb 7:46
Jẹ́n. 33:18Jẹ 25:20; 28:6
Jẹ́n. 33:18Joṣ 24:1
Jẹ́n. 33:18Jẹ 10:19; 12:6
Jẹ́n. 33:19Joṣ 24:32; Iṣe 7:15, 16
Jẹ́n. 33:20Jẹ 35:1, 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 33:1-20

Jẹ́nẹ́sísì

33 Jékọ́bù bá wòkè, ó sì rí Ísọ̀ tó ń bọ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.+ Torí náà, ó pín àwọn ọmọ sọ́dọ̀ Líà, Réṣẹ́lì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ méjèèjì. 2 Ó fi àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà àti àwọn ọmọ wọn síwájú,+ Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀ lé wọn,+ Réṣẹ́lì+ àti Jósẹ́fù sì wà lẹ́yìn wọn. 3 Òun fúnra rẹ̀ wá ṣíwájú wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀meje bó ṣe ń sún mọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

4 Àmọ́ Ísọ̀ sáré pàdé rẹ̀, ó gbá a mọ́ra, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n sì bú sẹ́kún. 5 Nígbà tó gbójú sókè, tó sì rí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ náà, ó bi í pé: “Àwọn wo ló wà pẹ̀lú rẹ yìí?” Ó fèsì pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi bù kún ìránṣẹ́+ rẹ ni.” 6 Àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà wá bọ́ síwájú pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì tẹrí ba, 7 Líà náà bọ́ síwájú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba. Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù bọ́ síwájú pẹ̀lú Réṣẹ́lì, wọ́n sì tẹrí ba.+

8 Ísọ̀ bi Jékọ́bù pé: “Kí ni gbogbo àwùjọ àwọn arìnrìn-àjò tí mo pàdé+ yìí wà fún?” Ó fèsì pé: “Kí n lè rí ojúure olúwa+ mi ni.” 9 Ísọ̀ wá sọ pé: “Àbúrò mi,+ mo ní àwọn ohun tó pọ̀ gan-an. Máa mú àwọn nǹkan rẹ lọ.” 10 Àmọ́ Jékọ́bù sọ pé: “Jọ̀ọ́, má ṣe bẹ́ẹ̀. Tí mo bá rí ojúure rẹ, wàá gba ẹ̀bùn tí mo fún ọ lọ́wọ́ mi, torí kí n lè rí ojú rẹ ni mo ṣe mú un wá. Mo sì ti rí ojú rẹ, ó dà bí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọ́run, torí o gbà mí tayọ̀tayọ̀.+ 11 Jọ̀ọ́, gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ+ láti bù kún ọ, torí Ọlọ́run ti ṣojúure sí mi, mo sì ní gbogbo ohun tí mo nílò.”+ Ó sì ń rọ̀ ọ́ títí ó fi gbà á.

12 Nígbà tó yá, Ísọ̀ sọ pé: “Jẹ́ ká ṣí kúrò, ká sì máa lọ. Jẹ́ kí n máa lọ níwájú rẹ.” 13 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Olúwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára,+ mo sì ní àwọn àgùntàn àti màlúù tó ń tọ́mọ lọ́wọ́. Tí mo bá yára dà wọ́n jù láàárín ọjọ́ kan, gbogbo ẹran ló máa kú. 14 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí olúwa mi máa lọ níwájú ìránṣẹ́ rẹ̀, èmi á rọra máa bọ̀ bí agbára àwọn ẹran ọ̀sìn mi àti àwọn ọmọ mi bá ṣe gbé e, títí màá fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Séírì.”+ 15 Ísọ̀ wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n fi díẹ̀ lára àwọn èèyàn mi sílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ.” Ó fèsì pé: “Má ṣèyọnu, jẹ́ kí n ṣáà rí ojúure olúwa mi.” 16 Ísọ̀ sì pa dà sí Séírì ní ọjọ́ yẹn.

17 Jékọ́bù wá lọ sí Súkótù,+ ó kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe àtíbàbà fún agbo ẹran rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ ibẹ̀ ní Súkótù.*

18 Jékọ́bù rìnrìn àjò wá láti Padani-árámù,+ ó sì dé sí ìlú Ṣékémù+ ní ilẹ̀ Kénáánì+ ní àlàáfíà, ó wá pàgọ́ sí tòsí ìlú náà. 19 Ó ra apá kan lára ilẹ̀ tó pa àgọ́ rẹ̀ sí lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì, bàbá Ṣékémù, ó rà á ní ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó.+ 20 Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pè é ní Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́