Jóòbù
29 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀* rẹ̀ lọ, ó ní:
2 “Ká sọ pé àwọn oṣù tó ti kọjá ni mo wà,
Láwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run ń ṣọ́ mi,
3 Nígbà tó mú kí fìtílà rẹ̀ tàn sí mi lórí,
Nígbà tí mo fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ rìn nínú òkùnkùn,+
4 Nígbà tí mo ṣì lókun,*
Nígbà tí mo mọ bó ṣe ń rí kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nínú àgọ́ mi,+
5 Nígbà tí Olódùmarè ṣì wà pẹ̀lú mi,
Nígbà tí àwọn ọmọ* mi yí mi ká,
6 Nígbà tí bọ́tà bo àwọn ìṣísẹ̀ mi,
Tí àwọn àpáta sì ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi.+
7 Nígbà tí mo ṣì máa ń jáde lọ sí ẹnubodè ìlú,+
Tí mo sì máa ń jókòó sí ojúde ìlú,+
8 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa rí mi, wọ́n á sì yà sẹ́gbẹ̀ẹ́,*
Àwọn àgbà ọkùnrin pàápàá máa dìde, wọ́n á sì wà ní ìdúró.+
9 Àwọn ìjòyè máa ń dákẹ́;
Wọ́n á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.
10 Àwọn gbajúmọ̀ ọkùnrin panu mọ́;
Ahọ́n wọn lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn.
11 Ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ mi máa ń sọ̀rọ̀ mi dáadáa,
Àwọn tó sì rí mi máa ń ṣe ẹlẹ́rìí mi.
14 Mo wọ òdodo bí aṣọ;
Ìdájọ́ òdodo mi dà bí ẹ̀wù* àti láwàní.
15 Mo di ojú fún afọ́jú
Àti ẹsẹ̀ fún arọ.
17 Mo máa ń fọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹni burúkú,+
Mo sì máa ń já ẹran gbà kúrò ní eyín rẹ̀.
19 Màá ta gbòǹgbò wọnú omi,
Ìrì á sì wà lórí àwọn ẹ̀ka mi mọ́jú.
20 Ògo mi ń di ọ̀tun ní gbogbo ìgbà,
Màá sì máa ta ọfà ọwọ́ mi léraléra.’
21 Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ mi,
Wọ́n á dákẹ́, wọ́n á máa retí ìmọ̀ràn mi.+
22 Tí mo bá ti sọ̀rọ̀, wọn kì í tún ní ohunkóhun láti sọ;
Ọ̀rọ̀ mi máa ń rọra wọ̀ wọ́n* létí.
23 Wọ́n ń dúró dè mí bí ẹni ń dúró de òjò;
Wọ́n la ẹnu wọn sílẹ̀ gbayawu bíi fún òjò ìrúwé.+