ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

      • Ibojì ṣófo (1-10)

      • Jésù fara han Màríà Magidalénì (11-18)

      • Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (19-23)

      • Tọ́másì ṣiyèméjì, àmọ́ ó pa dà dá a lójú (24-29)

      • Ìdí tí wọ́n fi kọ àkájọ ìwé yìí (30, 31)

Jòhánù 20:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibojì ìrántí.”

  • *

    Tàbí “ibojì ìrántí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 28:1; Mk 16:1, 2
  • +Lk 24:1-3

Jòhánù 20:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 13:23; 19:26; 21:24
  • +Jo 19:41, 42

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 304

Jòhánù 20:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:40

Jòhánù 20:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    1/8/1999, ojú ìwé 22

Jòhánù 20:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    1/8/1999, ojú ìwé 22

Jòhánù 20:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 16:10; Mt 16:21; Iṣe 2:27

Jòhánù 20:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mk 16:5

Jòhánù 20:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 24:15, 16, 30, 31; Jo 21:4

Jòhánù 20:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 28:10
  • +Jo 14:28; 16:28
  • +1Kọ 11:3; Ef 1:17; Kol 1:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 19

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 32

    12/1/2004, ojú ìwé 31

Jòhánù 20:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 24:9, 10

Jòhánù 20:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 24:36

Jòhánù 20:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:34
  • +Jo 16:22

Jòhánù 20:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 24:36
  • +Ais 61:1; Jo 5:36
  • +Mt 28:19, 20; Jo 17:18

Jòhánù 20:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:2, 4

Jòhánù 20:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/15/1996, ojú ìwé 28-29

    3/15/1991, ojú ìwé 6

Jòhánù 20:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:16

Jòhánù 20:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:34

Jòhánù 20:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 20:19

Jòhánù 20:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “jẹ́ aláìnígbàgbọ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2004, ojú ìwé 31

Jòhánù 20:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 307

    Jí!,

    5/8/2005, ojú ìwé 21

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1992, ojú ìwé 23

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 28-29

Jòhánù 20:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 21:25

Jòhánù 20:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:15; 5:24; 1Pe 1:8, 9; 1Jo 5:13

Àwọn míì

Jòh. 20:1Mt 28:1; Mk 16:1, 2
Jòh. 20:1Lk 24:1-3
Jòh. 20:2Jo 13:23; 19:26; 21:24
Jòh. 20:2Jo 19:41, 42
Jòh. 20:5Jo 19:40
Jòh. 20:9Sm 16:10; Mt 16:21; Iṣe 2:27
Jòh. 20:12Mk 16:5
Jòh. 20:14Lk 24:15, 16, 30, 31; Jo 21:4
Jòh. 20:17Mt 28:10
Jòh. 20:17Jo 14:28; 16:28
Jòh. 20:171Kọ 11:3; Ef 1:17; Kol 1:3
Jòh. 20:18Lk 24:9, 10
Jòh. 20:19Lk 24:36
Jòh. 20:20Jo 19:34
Jòh. 20:20Jo 16:22
Jòh. 20:21Lk 24:36
Jòh. 20:21Ais 61:1; Jo 5:36
Jòh. 20:21Mt 28:19, 20; Jo 17:18
Jòh. 20:22Iṣe 2:2, 4
Jòh. 20:24Jo 11:16
Jòh. 20:25Jo 19:34
Jòh. 20:26Jo 20:19
Jòh. 20:30Jo 21:25
Jòh. 20:31Jo 3:15; 5:24; 1Pe 1:8, 9; 1Jo 5:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù 20:1-31

Àkọsílẹ̀ Jòhánù

20 Ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì wá síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù,+ nígbà tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó sì rí i pé wọ́n ti gbé òkúta náà kúrò níbi ibojì* náà.+ 2 Ló bá sáré wá bá Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́ gan-an,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì,+ a ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”

3 Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì wá gbéra lọ síbi ibojì náà. 4 Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ sáré, àmọ́ ọmọ ẹ̀yìn kejì yára ju Pétérù lọ, òun ló sì kọ́kọ́ dé ibojì náà. 5 Ó wá bẹ̀rẹ̀ wo iwájú, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀* nílẹ̀ níbẹ̀,+ àmọ́ kò wọlé. 6 Símónì Pétérù náà dé lẹ́yìn rẹ̀, ó sì wọnú ibojì náà. Ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ nílẹ̀ níbẹ̀. 7 Aṣọ tó wà ní orí rẹ̀ kò sí níbi tí aṣọ yòókù tí wọ́n fi dì í wà, àmọ́ ó dá wà níbì kan, ní kíká jọ. 8 Ọmọ ẹ̀yìn kejì tó kọ́kọ́ dé ibojì náà wá wọlé, ó rí i, ó sì gbà gbọ́. 9 Torí ìwé mímọ́ ò tíì yé wọn pé ó gbọ́dọ̀ jíǹde.+ 10 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà pa dà sí ilé wọn.

11 Àmọ́ Màríà ò kúrò níbi tó dúró sí níta nítòsí ibojì náà, ó ń sunkún. Bó ṣe ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ wo inú ibojì náà, 12 ó sì rí áńgẹ́lì méjì+ tó wọ aṣọ funfun tí wọ́n jókòó síbi tí wọ́n tẹ́ Jésù sí tẹ́lẹ̀, ọ̀kan níbi orí, ọ̀kan níbi ẹsẹ̀. 13 Wọ́n sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tó ò ń sunkún?” Ó sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, mi ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” 14 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó yíjú pa dà, ó sì rí Jésù tó dúró síbẹ̀, àmọ́ kò mọ̀ pé Jésù ni.+ 15 Jésù sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tí o fi ń sunkún? Ta lò ń wá?” Obìnrin náà rò pé ẹni tó ń tọ́jú ọgbà ni, ló bá sọ fún un pé: “Ọ̀gá, tó bá jẹ́ ìwọ lo gbé e kúrò, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, màá sì gbé e lọ.” 16 Jésù sọ fún un pé: “Màríà!” Ló bá yíjú pa dà, ó sì sọ fún un ní èdè Hébérù pé: “Rábónì!” (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́!”) 17 Jésù sọ fún un pé: “Má rọ̀ mọ́ mi mọ́, torí mi ò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba. Àmọ́ lọ bá àwọn arákùnrin mi,+ kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi+ àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi+ àti Ọlọ́run yín.’” 18 Màríà Magidalénì wá ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Mo ti rí Olúwa!” Ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó sọ fún òun.+

19 Nígbà tí ọjọ́ ti lọ lọ́jọ́ yẹn, ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, tí ilẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà sì wà ní títì pa torí pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù, Jésù wá, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 20 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀+ hàn wọ́n. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì dùn pé wọ́n rí Olúwa.+ 21 Jésù tún sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.+ Bí Baba ṣe rán mi gẹ́lẹ́+ ni èmi náà ń rán yín.”+ 22 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó fẹ́ atẹ́gùn sí wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́.+ 23 Tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ẹnikẹ́ni, wọ́n á rí ìdáríjì; tí ẹ bá ní kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni ṣì wà, wọ́n ṣì máa wà.”

24 Àmọ́ Tọ́másì,+ ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Ìbejì, kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí Jésù wá. 25 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ń sọ fún un pé: “A ti rí Olúwa!” Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Láìjẹ́ pé mo rí àpá* ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, tí mo ki ìka mi bọ àpá ìṣó náà, tí mo sì ki ọwọ́ mi bọ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ mi ò ní gbà gbọ́ láé.”

26 Ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún wà nínú ilé, Tọ́másì sì wà pẹ̀lú wọn. Jésù wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ilẹ̀kùn pa, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 27 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Tọ́másì pé: “Fi ìka rẹ síbí, kí o sì wo ọwọ́ mi, ki ọwọ́ rẹ bọ ẹ̀gbẹ́ mi, kí o má sì ṣiyèméjì* mọ́, àmọ́ kí o gbà gbọ́.” 28 Tọ́másì dá a lóhùn pé: “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!” 29 Jésù sọ fún un pé: “Ṣé o ti wá gbà gbọ́ torí pé o rí mi? Aláyọ̀ ni àwọn tí kò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà gbọ́.”

30 Ó dájú pé Jésù tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì míì níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tí a ò kọ sínú àkájọ ìwé yìí.+ 31 Àmọ́ a kọ àwọn yìí sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, kí ẹ sì lè ní ìyè nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ tí ẹ bá gbà gbọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́