Sekaráyà
11 “Ṣí àwọn ilẹ̀kùn rẹ, ìwọ Lẹ́bánónì,
Kí iná lè run àwọn igi kédárì rẹ.
2 Pohùn réré ẹkún, ìwọ igi júnípà, torí igi kédárì ti ṣubú;
Àwọn igi ńláńlá ti pa run!
Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin igi ràgàjì* ní Báṣánì,
Torí wọ́n ti gé igbó kìjikìji lulẹ̀!
3 Ẹ fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń pohùn réré ẹkún,
Torí ògo wọn ti wọmi.
Ẹ fetí sílẹ̀! Àwọn ọmọ kìnnìún* ń ké ramúramù,
Torí igbó tó wà lẹ́bàá Jọ́dánì ti pa run.
4 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run mi sọ nìyí, ‘Bójú tó agbo ẹran tí wọ́n fẹ́ pa,+ 5 àwọn tó ra àwọn ẹran náà pa wọ́n,+ wọn ò sì dá wọn lẹ́bi. Àwọn tó ń tà wọ́n+ sì sọ pé: “Ẹ yin Jèhófà, torí màá di ọlọ́rọ̀.” Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ò sì káàánú wọn.’+
6 “Jèhófà sọ pé, ‘Mi ò ní káàánú àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà mọ́. Torí náà, màá mú kí kálukú kó sí ọwọ́ ọmọnìkejì rẹ̀ àti sí ọwọ́ ọba rẹ̀; wọ́n á pa ilẹ̀ náà run, mi ò sì ní gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ wọn.’”
7 Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó agbo ẹran tí wọ́n fẹ́ pa,+ ẹ̀yin tí ìyà ń jẹ nínú agbo ẹran ni mo sì ṣe é fún. Torí náà, mo mú ọ̀pá méjì, mo pe ọ̀kan ní Adùn, mo sì pe èkejì ní Ìṣọ̀kan,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran. 8 Ní oṣù kan, mo lé olùṣọ́ àgùntàn mẹ́ta kúrò lẹ́nu iṣẹ́, torí ọ̀rọ̀ wọn sú mi,* àwọn* pẹ̀lú sì kórìíra mi. 9 Mo sì sọ pé: “Mi ò ní ṣe olùṣọ́ àgùntàn yín mọ́. Kí ẹni tó ń kú lọ kú, kí ẹni tó ń ṣègbé lọ sì ṣègbé. Ní ti àwọn tó ṣẹ́ kù, kí wọ́n jẹ ẹran ara wọn.” 10 Torí náà, mo mú ọ̀pá mi tó ń jẹ́ Adùn,+ mo sì kán an, mo sì fagi lé májẹ̀mú mi tí mo bá gbogbo àwọn èèyàn náà dá. 11 Mo fagi lé e lọ́jọ́ yẹn, àwọn tí ìyà ń jẹ nínú agbo ẹran tó ń wò mí sì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ni.
12 Ni mo bá sọ fún wọn pé: “Tó bá dára lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́; tí kò bá sì dára lójú yín, ẹ mú un dání.” Wọ́n sì san* owó iṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.+
13 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Sọ owó náà sí ibi ìṣúra, iye tó jọjú tí wọ́n rò pé ó tọ́ sí mi.”+ Torí náà, mo mú ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà, mo sì sọ ọ́ sí ibi ìṣúra ní ilé Jèhófà.+
14 Lẹ́yìn náà, mo kán ọ̀pá mi kejì tó ń jẹ́ Ìṣọ̀kan,+ mo sì ba àjọṣe tó wà láàárín Júdà àti Ísírẹ́lì jẹ́.+
15 Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Ó yá, lọ sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan tí kò wúlò, kí o sì mú irinṣẹ́ rẹ̀.+ 16 Torí èmi yóò gbé olùṣọ́ àgùntàn kan dìde ní ilẹ̀ náà. Kò ní tọ́jú àwọn àgùntàn tó ń ṣègbé lọ;+ kò ní wá àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn, kò ní tọ́jú àwọn tó fara pa,+ kò sì ní bọ́ àwọn tó lókun láti dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ ẹran ara àwọn tó sanra,+ á sì ya pátákò àwọn àgùntàn.+
17 O gbé, ìwọ olùṣọ́ àgùntàn mi tí kò wúlò,+ tó ń pa agbo ẹran tì!+
Idà yóò ṣá a ní apá àti ojú ọ̀tún rẹ̀.
Apá rẹ̀ á rọ pátápátá,
Ojú ọ̀tún rẹ̀ á sì fọ́ yán-án yán-án.”*