ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sítà 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítà

      • Ẹ́sítà tú Hámánì fó (1-6a)

      • Wọ́n gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi tó ṣe (6b-10)

Ẹ́sítà 7:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 3:1

Ẹ́sítà 7:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “jẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 5:3, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 140

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 26

Ẹ́sítà 7:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 2:5, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 140-141

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 26

Ẹ́sítà 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 3:8, 9
  • +Ẹst 3:13; 4:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 141

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 26-27

    3/1/2006, ojú ìwé 11

Ẹ́sítà 7:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 141-142

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 27

Ẹ́sítà 7:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 141-142

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 27

Ẹ́sítà 7:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 142

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 27

    3/1/2006, ojú ìwé 11

Ẹ́sítà 7:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Nǹkan bíi mítà 22.3 (ẹsẹ̀ bàtà 73). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 1:10
  • +Ẹst 5:14
  • +Ẹst 6:2

Àwọn míì

Ẹ́sít. 7:1Ẹst 3:1
Ẹ́sít. 7:2Ẹst 5:3, 6
Ẹ́sít. 7:3Ẹst 2:5, 7
Ẹ́sít. 7:4Ẹst 3:8, 9
Ẹ́sít. 7:4Ẹst 3:13; 4:7, 8
Ẹ́sít. 7:9Ẹst 1:10
Ẹ́sít. 7:9Ẹst 5:14
Ẹ́sít. 7:9Ẹst 6:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́sítà 7:1-10

Ẹ́sítà

7 Nígbà náà, ọba àti Hámánì+ wá sí ibi àsè Ẹ́sítà Ayaba. 2 Ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà ní ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n ń mu wáìnì lọ́wọ́ pé: “Ẹ́sítà Ayaba, kí lo fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ. Kí lo sì fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó ṣe é fún ọ!”+ 3 Ẹ́sítà Ayaba fèsì pé: “Tí mo bá rí ojú rere rẹ, ọba, tó bá sì wu ọba, ohun tí mo fẹ́ tọrọ ni pé kí a fún mi ní ẹ̀mí* mi, ohun tí mo sì fẹ́ béèrè ni pé kí a fún mi ní àwọn èèyàn mi.+ 4 Nítorí wọ́n ti ta+ èmi àti àwọn èèyàn mi, láti pa wá, láti run wá àti láti pa wá rẹ́.+ Ká ní wọ́n kàn tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin nìkan ni, mi ò bá dákẹ́. Àmọ́ àjálù náà kò ní bọ́ sí i rárá torí pé ó máa pa ọba lára.”

5 Ọba Ahasuérúsì wá béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà Ayaba pé: “Ta ni? Ibo lẹni tó gbójúgbóyà ṣerú èyí wà?” 6 Ẹ́sítà sọ pé: “Elénìní àti ọ̀tá náà ni Hámánì olubi yìí.”

Jìnnìjìnnì bo Hámánì nítorí ọba àti ayaba. 7 Ọba fi ìbínú dìde kúrò nídìí wáìnì, ó sì lọ sí ọgbà ààfin, àmọ́ Hámánì dìde láti bẹ Ẹ́sítà Ayaba nítorí ẹ̀mí* rẹ̀, torí ó mọ̀ pé ọba ti pinnu láti fìyà jẹ òun. 8 Ọba pa dà wá láti ọgbà ààfin sí ilé tí wọ́n ti ń mu wáìnì, ó sì rí Hámánì tó nà lé àga tìmùtìmù tí Ẹ́sítà wà. Ọba kọ hàà pé: “Ṣé ó tún fẹ́ fipá bá ayaba lò pọ̀ nínú ilé mi ni?” Bí ọba ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n bo Hámánì lójú. 9 Hábónà,+ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba wá sọ pé: “Hámánì tún ṣe òpó igi kan fún Módékáì,+ ẹni tó sọ ohun tó gba ọba sílẹ̀.+ Òpó náà wà ní òró ní ilé Hámánì, àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́* ni gíga rẹ̀.” Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ gbé e kọ́ sórí rẹ̀.” 10 Torí náà, wọ́n gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi tó ṣe fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọlẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́