ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún aráyé (1-7)

        • Òfin nípa ẹ̀jẹ̀ (4-6)

      • Májẹ̀mú tí Ọlọ́run fi òṣùmàrè dá (8-17)

      • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà (18-29)

Jẹ́nẹ́sísì 9:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:28

Jẹ́nẹ́sísì 9:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ ti ní àṣẹ lórí wọn báyìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:26; Jem 3:7

Jẹ́nẹ́sísì 9:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ti 4:3
  • +Jẹ 1:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 14-15

    Jí!,

    8/8/1997, ojú ìwé 18-20

Jẹ́nẹ́sísì 9:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:11, 14
  • +Le 3:17; 7:26; 17:10, 13; Di 12:16, 23; Iṣe 15:20, 29; 21:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 39

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 75

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 14-15, 20

    6/15/1991, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 9:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀jẹ̀ ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:8, 10; Ẹk 21:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 75

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 15

    11/15/1995, ojú ìwé 10

    6/15/1991, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:13; Nọ 35:30; Mt 26:52
  • +Jẹ 1:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 15

    11/15/1995, ojú ìwé 10, 12

    Jí!,

    3/8/1996, ojú ìwé 22

Jẹ́nẹ́sísì 9:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:28; 10:32

Jẹ́nẹ́sísì 9:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:15; Ais 54:9

Jẹ́nẹ́sísì 9:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “alààyè ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:17

Jẹ́nẹ́sísì 9:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun alààyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:21

Jẹ́nẹ́sísì 9:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “alààyè ọkàn.”

Jẹ́nẹ́sísì 9:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 79

Jẹ́nẹ́sísì 9:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo alààyè ọkàn tó jẹ́ ẹlẹ́ran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:21

Jẹ́nẹ́sísì 9:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo alààyè ọkàn tó jẹ́ ẹlẹ́ran ara.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 15

Jẹ́nẹ́sísì 9:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:12, 13

Jẹ́nẹ́sísì 9:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 5:32; 7:7; 10:1
  • +Jẹ 10:6

Jẹ́nẹ́sísì 9:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:32

Jẹ́nẹ́sísì 9:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹrú àwọn ẹrú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:1
  • +Joṣ 17:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2004, ojú ìwé 31

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 80-81

Jẹ́nẹ́sísì 9:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 1:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 26

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 80-81

Jẹ́nẹ́sísì 9:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/1998, ojú ìwé 29

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 80-81

Jẹ́nẹ́sísì 9:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:6

Àwọn míì

Jẹ́n. 9:1Jẹ 1:28
Jẹ́n. 9:2Jẹ 1:26; Jem 3:7
Jẹ́n. 9:31Ti 4:3
Jẹ́n. 9:3Jẹ 1:29
Jẹ́n. 9:4Le 17:11, 14
Jẹ́n. 9:4Le 3:17; 7:26; 17:10, 13; Di 12:16, 23; Iṣe 15:20, 29; 21:25
Jẹ́n. 9:5Jẹ 4:8, 10; Ẹk 21:12
Jẹ́n. 9:6Ẹk 20:13; Nọ 35:30; Mt 26:52
Jẹ́n. 9:6Jẹ 1:27
Jẹ́n. 9:7Jẹ 1:28; 10:32
Jẹ́n. 9:9Jẹ 9:15; Ais 54:9
Jẹ́n. 9:10Jẹ 8:17
Jẹ́n. 9:11Jẹ 8:21
Jẹ́n. 9:15Jẹ 8:21
Jẹ́n. 9:17Jẹ 9:12, 13
Jẹ́n. 9:18Jẹ 5:32; 7:7; 10:1
Jẹ́n. 9:18Jẹ 10:6
Jẹ́n. 9:19Jẹ 10:32
Jẹ́n. 9:25Di 7:1
Jẹ́n. 9:25Joṣ 17:13
Jẹ́n. 9:26Ond 1:28
Jẹ́n. 9:28Jẹ 7:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 9:1-29

Jẹ́nẹ́sísì

9 Ọlọ́run súre fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ pọ̀, kí ẹ sì kún ayé.+ 2 Gbogbo ohun alààyè tó wà láyé, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀ àti gbogbo ẹja inú òkun yóò máa bẹ̀rù yín, wọ́n á sì máa wárìrì torí yín. Wọ́n ti wà ní ìkáwọ́ yín báyìí.*+ 3 Gbogbo ẹran tó ń rìn tó sì wà láàyè lè jẹ́ oúnjẹ fún yín.+ Mo fún yín ní gbogbo wọn bí mo ṣe fún yín ní ewéko tútù.+ 4 Kìkì ẹran pẹ̀lú ẹ̀mí* rẹ̀, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ.+ 5 Yàtọ̀ sí ìyẹn, èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ yín tó jẹ́ ẹ̀mí yín* pa dà. Èmi yóò béèrè lọ́wọ́ gbogbo ohun alààyè; ọwọ́ kálukú ni màá sì ti béèrè ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀.+ 6 Ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀, èèyàn ni yóò ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀,+ torí àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá èèyàn.+ 7 Ní tiyín, ẹ máa bímọ, kí ẹ pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ.”+

8 Ọlọ́run wá sọ fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: 9 “Mò ń bá ẹ̀yin  + àti àwọn ọmọ yín dá májẹ̀mú, 10 àti gbogbo ohun alààyè* tó wà pẹ̀lú yín, àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran àti gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé pẹ̀lú yín, gbogbo àwọn tó tinú áàkì jáde, ìyẹn gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé.+ 11 Àní, mo fìdí májẹ̀mú tí mo bá yín dá múlẹ̀: Ìkún omi ò tún ní pa gbogbo ẹran ara* run mọ́, ìkún omi ò sì ní pa ayé run mọ́.”+

12 Ọlọ́run sì fi kún un pé: “Àmì májẹ̀mú tí mò ń bá ẹ̀yin àti gbogbo ohun alààyè* tó wà pẹ̀lú yín dá nìyí, jálẹ̀ gbogbo ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. 13 Mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, ó sì máa jẹ́ àmì májẹ̀mú tó wà láàárín èmi àti ayé. 14 Nígbàkigbà tí mo bá mú kí ojú ọ̀run ṣú, ó dájú pé òṣùmàrè máa hàn lójú ọ̀run. 15 Ó sì dájú pé màá rántí májẹ̀mú tí mo bá ẹ̀yin àti onírúurú ohun alààyè* dá; omi ò sì tún ní pọ̀ mọ́ débi tó fi máa kún, tó sì máa pa gbogbo ẹran ara run.+ 16 Òṣùmàrè á yọ lójú ọ̀run, ó sì dájú pé màá rí i, màá sì rántí májẹ̀mú ayérayé tó wà láàárín Ọlọ́run àti onírúurú ohun alààyè* tó wà ní ayé.”

17 Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé: “Àmì májẹ̀mú tí mo bá gbogbo ẹran ara tó wà ní ayé dá nìyí.”+

18 Àwọn ọmọ Nóà tó jáde nínú áàkì ni Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì.+ Nígbà tó yá, Hámù bí Kénáánì.+ 19 Àwọn mẹ́ta yìí ni ọmọ Nóà, àwọn ló sì bí gbogbo èèyàn tó wà ní ayé, tí wọ́n sì tàn káàkiri.+

20 Nóà wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà kan. 21 Nígbà tó mu lára wáìnì rẹ̀, ọtí bẹ̀rẹ̀ sí í pa á, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò nínú àgọ́ rẹ̀. 22 Hámù, bàbá Kénáánì, rí ìhòòhò bàbá rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjèèjì níta. 23 Ṣémù àti Jáfẹ́tì wá mú aṣọ kan, wọ́n fi lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn wọlé. Wọ́n bo ìhòòhò bàbá wọn, àmọ́ wọn ò wo ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn ò sì rí ìhòòhò bàbá wọn.

24 Nígbà tí wáìnì dá lójú Nóà, ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, 25 ó sì sọ pé:

“Ègún ni fún Kénáánì.+

Kó di ẹrú àwọn arákùnrin rẹ̀.”*+

26 Ó sì fi kún un pé:

“Ẹ yin Jèhófà, Ọlọ́run Ṣémù,

Kí Kénáánì sì di ẹrú rẹ̀.+

27 Kí Ọlọ́run fún Jáfẹ́tì ní àyè tó fẹ̀ dáadáa,

Kó sì máa gbé inú àwọn àgọ́ Ṣémù.

Kí Kénáánì di ẹrú tiẹ̀ náà.”

28 Nóà lo ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta (350) ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi.+ 29 Torí náà, gbogbo ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé àádọ́ta (950) ọdún, ó sì kú.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́