ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Àdéhùn tí Ásà bá Síríà ṣe (1-6)

      • Hánáánì bá Ásà wí (7-10)

      • Ikú Ásà (11-14)

2 Kíróníkà 16:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ odi; tún Rámà kọ́.”

  • *

    Tàbí “sí ìpínlẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:25, 27
  • +Joṣ 18:21, 25
  • +1Ọb 15:17-19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2012, ojú ìwé 10

2 Kíróníkà 16:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:51
  • +1Ọb 20:1; 2Ọb 12:18; 16:8

2 Kíróníkà 16:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Májẹ̀mú.”

  • *

    Tàbí “májẹ̀mú.”

2 Kíróníkà 16:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 15:29
  • +Ond 18:29
  • +1Ọb 15:20-22

2 Kíróníkà 16:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mímọ odi; títún Rámà kọ́.”

2 Kíróníkà 16:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ odi; tún Gébà kọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:21, 25
  • +1Ọb 15:17
  • +Joṣ 18:21, 24; 1Kr 6:60, 64
  • +Joṣ 18:21, 26; Ond 20:1

2 Kíróníkà 16:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbára lé.”

  • *

    Ní Héb., “gbára lé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:1; 2Kr 19:2; 20:34
  • +Jer 17:5

2 Kíróníkà 16:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 14:9, 11; Sm 37:39, 40

2 Kíróníkà 16:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtìlẹ́yìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 4:10
  • +1Pe 3:12
  • +1Ọb 15:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 42-43

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2002, ojú ìwé 14

2 Kíróníkà 16:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “sí ilé àbà.”

2 Kíróníkà 16:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2009, ojú ìwé 32

2 Kíróníkà 16:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2012, ojú ìwé 10

2 Kíróníkà 16:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:24

2 Kíróníkà 16:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣe kedere pé, wọn ò finá sun òkú Ásà, àwọn èròjà ni wọ́n finá sun.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:7
  • +Mk 16:1; Lk 23:55, 56; Jo 19:40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 20

Àwọn míì

2 Kíró. 16:11Ọb 15:25, 27
2 Kíró. 16:1Joṣ 18:21, 25
2 Kíró. 16:11Ọb 15:17-19
2 Kíró. 16:21Ọb 7:51
2 Kíró. 16:21Ọb 20:1; 2Ọb 12:18; 16:8
2 Kíró. 16:42Ọb 15:29
2 Kíró. 16:4Ond 18:29
2 Kíró. 16:41Ọb 15:20-22
2 Kíró. 16:6Joṣ 18:21, 25
2 Kíró. 16:61Ọb 15:17
2 Kíró. 16:6Joṣ 18:21, 24; 1Kr 6:60, 64
2 Kíró. 16:6Joṣ 18:21, 26; Ond 20:1
2 Kíró. 16:71Ọb 16:1; 2Kr 19:2; 20:34
2 Kíró. 16:7Jer 17:5
2 Kíró. 16:82Kr 14:9, 11; Sm 37:39, 40
2 Kíró. 16:9Sek 4:10
2 Kíró. 16:91Pe 3:12
2 Kíró. 16:91Ọb 15:32
2 Kíró. 16:111Ọb 15:23
2 Kíró. 16:131Ọb 15:24
2 Kíró. 16:142Sa 5:7
2 Kíró. 16:14Mk 16:1; Lk 23:55, 56; Jo 19:40
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 16:1-14

Kíróníkà Kejì

16 Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì wá dojú kọ Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́* Rámà,+ kí ẹnikẹ́ni má bàa jáde tàbí kí ó wọlé sọ́dọ̀* Ásà ọba Júdà.+ 2 Ni Ásà bá kó fàdákà àti wúrà jáde látinú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọba Síríà+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: 3 “Àdéhùn* kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín bàbá mi àti bàbá rẹ. Mo fi fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wò ó, lọ yẹ àdéhùn* tí o bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe, kó lè pa dà lẹ́yìn mi.”

4 Bẹni-hádádì ṣe ohun tí Ọba Ásà sọ, ó rán àwọn olórí ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣá Íjónì,+ Dánì + àti Ebẹli-máímù balẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ibi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní àwọn ìlú Náfútálì.+ 5 Nígbà tí Bááṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú kíkọ́* Rámà, ó sì pa iṣẹ́ tó ń ṣe níbẹ̀ tì. 6 Ọba Ásà wá kó gbogbo Júdà jọ, wọ́n kó àwọn òkúta àti ẹ̀là gẹdú tó wà ní Rámà,+ tí Bááṣà fi ń kọ́lé,+ ó sì fi wọ́n kọ́* Gébà+ àti Mísípà.+

7 Ní àkókò yẹn, Hánáánì+ aríran wá bá Ásà ọba Júdà, ó sì sọ fún un pé: “Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé* ọba Síríà, tí o kò sì gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àwọn ọmọ ogun ọba Síríà ti bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.+ 8 Ṣebí àwọn ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà ní àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú àwọn agẹṣin? Àmọ́ torí pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+ 9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+

10 Àmọ́, inú bí Ásà sí aríran náà, ó sì fi í sẹ́wọ̀n,* torí ohun tó sọ mú kí Ásà gbaná jẹ. Ní àkókò yẹn kan náà, Ásà bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn kan lára àwọn èèyàn náà. 11 Ní ti ìtàn Ásà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.+

12 Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba Ásà, àrùn kan mú un ní ẹsẹ̀, ó sì di àìsàn ńlá sí i lára; síbẹ̀ nínú àìsàn tó wà, kò yíjú sí Jèhófà, àwọn oníṣègùn ló yíjú sí. 13 Níkẹyìn, Ásà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ ó kú ní ọdún kọkànlélógójì ìjọba rẹ̀. 14 Nítorí náà, wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú rẹ̀ tó lọ́lá, èyí tó gbẹ́ fún ara rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì;+ wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí àga ìgbókùú tí wọ́n ti fi òróró básámù sí lára àti oríṣiríṣi èròjà tí a pò mọ́ àkànṣe òróró ìpara.+ Síwájú sí i, wọ́n ṣe ìfinásun* tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí rẹ̀ nígbà ìsìnkú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́