Ìsíkíẹ́lì
6 Jèhófà tún sọ fún mi pé: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí àwọn òkè Ísírẹ́lì, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn. 3 Kí o sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ: Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn odò àti àwọn àfonífojì nìyí: “Wò ó! Èmi yóò fi idà bá yín jà, èmi yóò sì run àwọn ibi gíga yín. 4 Màá wó àwọn pẹpẹ yín, màá fọ́ àwọn ohun tí ẹ fi ń sun tùràrí,+ màá sì ju òkú àwọn èèyàn yín síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín.*+ 5 Èmi yóò ju òkú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun yín ká sí àyíká àwọn pẹpẹ yín.+ 6 Ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, àwọn ìlú yóò di ahoro,+ wọ́n á wó àwọn ibi gíga, yóò sì di ahoro.+ Wọ́n á wó àwọn pẹpẹ yín, wọ́n á sì tú u ká, àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín máa pa run, wọ́n á wó àwọn ohun tí ẹ fi ń sun tùràrí, iṣẹ́ yín á sì pa rẹ́. 7 Òkú á sùn lọ bẹẹrẹbẹ láàárín yín,+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
8 “‘“Àmọ́ màá mú kí àwọn kan ṣẹ́ kù, torí àwọn kan lára yín á bọ́ lọ́wọ́ idà àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí ẹ bá fọ́n ká sí àwọn ilẹ̀.+ 9 Àwọn tó bá yè bọ́ yóò rántí mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó kó wọn lẹ́rú.+ Wọ́n á rí i pé ó dùn mí gan-an bí ọkàn àìṣòótọ́* wọn ṣe mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi+ àti bí ojú wọn ṣe mú kí ọkàn wọn fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.*+ Gbogbo iṣẹ́ ibi àtàwọn ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe yóò kó ìtìjú bá wọn, wọ́n á sì kórìíra rẹ̀ gidigidi.+ 10 Wọ́n á sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà àti pé àjálù yìí tí mo sọ pé màá mú bá wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán.”’+
11 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Pàtẹ́wọ́, kí o fẹsẹ̀ kilẹ̀, kí o sì kẹ́dùn torí gbogbo ìwà ibi àti ohun tó ń ríni lára tí ilé Ísírẹ́lì ṣe, torí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa wọ́n.+ 12 Àjàkálẹ̀ àrùn yóò pa ẹni tó wà lọ́nà jíjìn, idà yóò pa ẹni tó wà nítòsí, ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù, tó sì bọ́ lọ́wọ́ ìwọ̀nyí ni ìyàn yóò pa; bí mo ṣe máa bínú sí wọn gidigidi nìyẹn.+ 13 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ bẹẹrẹbẹ níbi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, tí àwọn òkú náà yí àwọn pẹpẹ wọn ká,+ lórí gbogbo òkè kékeré àti òkè gíga, lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ àti lábẹ́ àwọn ẹ̀ka igi ńláńlá tí wọ́n ti rú àwọn ẹbọ olóòórùn dídùn* láti fi wá ojúure gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ 14 Èmi yóò na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ wọ́n, màá sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro, ibi tí wọ́n ń gbé máa di ahoro ju aginjù tó wà nítòsí Díbílà lọ. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”