Sáàmù
Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.
124 “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni”+
—Kí Ísírẹ́lì sọ pé—
2 “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni+
Nígbà tí àwọn èèyàn dìde láti bá wa jà,+
3 Wọn ì bá ti gbé wa mì láàyè+
Nígbà tí inú wọn ń ru sí wa.+
5 Omi tó ń ru gùdù ì bá ti bò wá* mọ́lẹ̀.
6 Ìyìn ni fún Jèhófà,
Torí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún eyín wọn.
8 Ìrànlọ́wọ́ wa wà nínú orúkọ Jèhófà,+
Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.”