ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 48
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jékọ́bù súre fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù méjèèjì (1-12)

      • Ìbùkún Éfúrémù ló pọ̀ jù (13-22)

Jẹ́nẹ́sísì 48:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:50; Joṣ 14:4

Jẹ́nẹ́sísì 48:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:13, 19; Ho 12:4

Jẹ́nẹ́sísì 48:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:10, 11
  • +Jẹ 28:13, 14

Jẹ́nẹ́sísì 48:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 14:4; 1Kr 5:1
  • +Jẹ 35:23

Jẹ́nẹ́sísì 48:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:29; 16:5

Jẹ́nẹ́sísì 48:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:19
  • +Mik 5:2
  • +1Sa 17:12; Mt 2:6

Jẹ́nẹ́sísì 48:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:50
  • +Heb 11:21

Jẹ́nẹ́sísì 48:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:34, 35; 42:36; 46:30

Jẹ́nẹ́sísì 48:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:52
  • +Jẹ 41:51

Jẹ́nẹ́sísì 48:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:51; 46:20

Jẹ́nẹ́sísì 48:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 5:2
  • +Jẹ 17:1; 24:40
  • +Jẹ 28:13; Sm 23:1

Jẹ́nẹ́sísì 48:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:15; 31:11; Sm 34:7
  • +Jẹ 32:26
  • +Ẹk 1:7; Nọ 26:34, 37

Jẹ́nẹ́sísì 48:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:51

Jẹ́nẹ́sísì 48:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 2:18-21
  • +Nọ 1:32, 33

Jẹ́nẹ́sísì 48:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:21

Jẹ́nẹ́sísì 48:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 50:24
  • +Jẹ 15:14; 26:3; Di 31:8

Jẹ́nẹ́sísì 48:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ilẹ̀.” Ní Héb., “èjìká ilẹ̀.”

Àwọn míì

Jẹ́n. 48:1Jẹ 41:50; Joṣ 14:4
Jẹ́n. 48:3Jẹ 28:13, 19; Ho 12:4
Jẹ́n. 48:4Jẹ 35:10, 11
Jẹ́n. 48:4Jẹ 28:13, 14
Jẹ́n. 48:5Joṣ 14:4; 1Kr 5:1
Jẹ́n. 48:5Jẹ 35:23
Jẹ́n. 48:6Joṣ 13:29; 16:5
Jẹ́n. 48:7Jẹ 35:19
Jẹ́n. 48:7Mik 5:2
Jẹ́n. 48:71Sa 17:12; Mt 2:6
Jẹ́n. 48:9Jẹ 41:50
Jẹ́n. 48:9Heb 11:21
Jẹ́n. 48:11Jẹ 37:34, 35; 42:36; 46:30
Jẹ́n. 48:13Jẹ 41:52
Jẹ́n. 48:13Jẹ 41:51
Jẹ́n. 48:14Jẹ 41:51; 46:20
Jẹ́n. 48:151Kr 5:2
Jẹ́n. 48:15Jẹ 17:1; 24:40
Jẹ́n. 48:15Jẹ 28:13; Sm 23:1
Jẹ́n. 48:16Jẹ 28:15; 31:11; Sm 34:7
Jẹ́n. 48:16Jẹ 32:26
Jẹ́n. 48:16Ẹk 1:7; Nọ 26:34, 37
Jẹ́n. 48:18Jẹ 41:51
Jẹ́n. 48:19Nọ 2:18-21
Jẹ́n. 48:19Nọ 1:32, 33
Jẹ́n. 48:20Heb 11:21
Jẹ́n. 48:21Jẹ 50:24
Jẹ́n. 48:21Jẹ 15:14; 26:3; Di 31:8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 48:1-22

Jẹ́nẹ́sísì

48 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, ara bàbá rẹ ò yá.” Ló bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì dání lọ síbẹ̀, ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù.+ 2 Wọ́n sì sọ fún Jékọ́bù pé: “Jósẹ́fù ọmọ rẹ ti dé.” Torí náà, Ísírẹ́lì tiraka, ó sì dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. 3 Jékọ́bù wá sọ fún Jósẹ́fù pé:

“Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì nílẹ̀ Kénáánì, ó sì súre fún mi.+ 4 Ó sọ fún mi pé, ‘Màá mú kí o bímọ, màá sì mú kí o di púpọ̀, màá sọ ọ́ di àwùjọ àwọn èèyàn,+ màá sì fún àtọmọdọ́mọ* rẹ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní wọn títí láé.’+ 5 Tèmi+ ni àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí o bí ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní Íjíbítì. Éfúrémù àti Mánásè yóò di tèmi bí Rúbẹ́nì àti Síméónì ṣe jẹ́ tèmi.+ 6 Àmọ́ àwọn ọmọ tí o bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ tìrẹ. Orúkọ àwọn ẹ̀gbọ́n wọn ni wọ́n á máa fi pe ogún wọn.+ 7 Ní tèmi, nígbà tí mò ń bọ̀ láti Pádánì, Réṣẹ́lì kú+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nílẹ̀ Kénáánì, nígbà tí ọ̀nà ṣì jìn sí Éfúrátì.+ Mo sì sin ín níbẹ̀ lójú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+

8 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó sì bi í pé: “Àwọn wo nìyí?” 9 Jósẹ́fù dá a lóhùn pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fún mi níbí+ ni.” Ni Ísírẹ́lì bá sọ pé: “Jọ̀ọ́ mú wọn wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè súre fún wọn.”+ 10 Ojú Ísírẹ́lì ti di bàìbàì torí ó ti darúgbó, kò sì ríran dáadáa. Jósẹ́fù mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. Ísírẹ́lì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó sì gbá wọn mọ́ra. 11 Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mi ò rò pé mo lè rí ọ mọ́,+ àmọ́ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n tún rí ọmọ* rẹ.” 12 Jósẹ́fù wá gbé wọn kúrò ní orúnkún Ísírẹ́lì, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀.

13 Jósẹ́fù wá mú àwọn méjèèjì, ó mú Éfúrémù+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ tó jẹ́ apá òsì Ísírẹ́lì, ó sì mú Mánásè+ sí ọwọ́ òsì rẹ̀ tó jẹ́ apá ọ̀tún Ísírẹ́lì, ó mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. 14 Àmọ́ Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé orí Éfúrémù bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì gbé ọwọ́ òsì rẹ̀ lé orí Mánásè. Ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, torí Mánásè ni àkọ́bí.+ 15 Ó wá súre fún Jósẹ́fù, ó sì sọ pé:+

“Ọlọ́run tòótọ́, tí àwọn bàbá mi Ábúráhámù àti Ísákì bá rìn,+

Ọlọ́run tòótọ́ tó ń bójú tó mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí dòní,+

16 Áńgẹ́lì tó ń gbà mí lọ́wọ́ gbogbo àjálù,+ jọ̀ọ́ bù kún àwọn ọmọ+ yìí.

Jẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn bàbá mi, Ábúráhámù àti Ísákì,

Jẹ́ kí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ ní ayé.”+

17 Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé bàbá òun ò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì gbìyànjú láti mú ọwọ́ bàbá rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kó sì gbé e sórí Mánásè. 18 Jósẹ́fù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́ bàbá mi, àkọ́bí+ nìyí. Gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” 19 Àmọ́ bàbá rẹ̀ ò gbà, ó sì sọ pé: “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà á di èèyàn púpọ̀, yóò sì di ẹni ńlá. Àmọ́, àbúrò rẹ̀ máa jù ú lọ,+ àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò sì pọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè.”+ 20 Ó sì súre fún wọn ní ọjọ́+ yẹn, ó ní:

“Kí Ísírẹ́lì máa fi orúkọ rẹ súre pé,

‘Kí Ọlọ́run mú kí o dà bí Éfúrémù àti Mánásè.’”

Ó wá ń fi Éfúrémù ṣáájú Mánásè.

21 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, mi ò ní pẹ́ kú,+ àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní fi yín sílẹ̀, yóò sì mú yín pa dà sí ilẹ̀ àwọn baba ńlá+ yín. 22 Ní tèmi, ilẹ̀* tí mo fún ọ fi ọ̀kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ, èyí tí mo fi idà àti ọrun mi gbà lọ́wọ́ àwọn Ámórì.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́