ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ọlọ́run gba Sérà lọ́wọ́ Ábímélékì (1-18)

Jẹ́nẹ́sísì 20:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó jẹ́ àjèjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 13:18
  • +Nọ 13:26
  • +Jẹ 25:17, 18
  • +Jẹ 10:19; 26:6

Jẹ́nẹ́sísì 20:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:11-13; 20:11, 12
  • +Jẹ 12:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2015, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 20:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:17; Sm 105:14
  • +Di 22:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1995, ojú ìwé 12

Jẹ́nẹ́sísì 20:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn ni pé, kò tíì bá a ní àṣepọ̀.

  • *

    Tàbí “tó jẹ́ olódodo.”

Jẹ́nẹ́sísì 20:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:14, 15
  • +Job 42:8

Jẹ́nẹ́sísì 20:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:18, 19; 26:9, 10

Jẹ́nẹ́sísì 20:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:11, 12; 26:7

Jẹ́nẹ́sísì 20:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 11:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 12

Jẹ́nẹ́sísì 20:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:1
  • +Jẹ 12:13

Jẹ́nẹ́sísì 20:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ìbòjú ló jẹ́ fún ọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:2, 12

Jẹ́nẹ́sísì 20:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ti sé gbogbo ilé ọlẹ̀ pa ní ilé Ábímélékì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:17

Àwọn míì

Jẹ́n. 20:1Jẹ 13:18
Jẹ́n. 20:1Nọ 13:26
Jẹ́n. 20:1Jẹ 25:17, 18
Jẹ́n. 20:1Jẹ 10:19; 26:6
Jẹ́n. 20:2Jẹ 12:11-13; 20:11, 12
Jẹ́n. 20:2Jẹ 12:15
Jẹ́n. 20:3Jẹ 12:17; Sm 105:14
Jẹ́n. 20:3Di 22:22
Jẹ́n. 20:7Sm 105:14, 15
Jẹ́n. 20:7Job 42:8
Jẹ́n. 20:10Jẹ 12:18, 19; 26:9, 10
Jẹ́n. 20:11Jẹ 12:11, 12; 26:7
Jẹ́n. 20:12Jẹ 11:29
Jẹ́n. 20:13Jẹ 12:1
Jẹ́n. 20:13Jẹ 12:13
Jẹ́n. 20:16Jẹ 20:2, 12
Jẹ́n. 20:18Jẹ 12:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 20:1-18

Jẹ́nẹ́sísì

20 Ábúráhámù wá ṣí ibùdó rẹ̀ kúrò níbẹ̀+ lọ sí ilẹ̀ Négébù, ó sì ń gbé láàárín Kádéṣì+ àti Ṣúrì.+ Nígbà tó ń gbé* ní Gérárì,+ 2 Ábúráhámù tún sọ nípa Sérà ìyàwó rẹ̀ pé: “Àbúrò mi ni.”+ Ni Ábímélékì ọba Gérárì bá ránṣẹ́ pe Sérà, ó sì mú un sọ́dọ̀.+ 3 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ábímélékì sọ̀rọ̀ lójú àlá ní òru, ó sọ fún un pé: “Wò ó, o ti kú tán torí obìnrin tí o mú yìí,+ ó ti lọ́kọ, ìyàwó oníyàwó+ sì ni.” 4 Àmọ́ Ábímélékì kò tíì sún mọ́ ọn.* Torí náà, ó sọ pé: “Jèhófà, ṣé o máa pa orílẹ̀-èdè tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀* run ni? 5 Ṣebí ọkùnrin náà sọ fún mi pé, ‘Àbúrò mi ni,’ obìnrin náà sì sọ pé, ‘Ẹ̀gbọ́n mi ni’? Òótọ́ inú ni mo fi ṣe ohun tí mo ṣe yìí, ọwọ́ mi mọ́.” 6 Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un lójú àlá pé: “Mo mọ̀ pé òótọ́ inú lo fi ṣe ohun tí o ṣe, torí ẹ̀ ni mi ò fi jẹ́ kí o dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. 7 Dá ìyàwó ọkùnrin náà pa dà, torí wòlíì+ ni, ó máa bá ọ bẹ̀bẹ̀,+ o ò sì ní kú. Àmọ́ tí o kò bá dá a pa dà, ó dájú pé wàá kú, ìwọ àti gbogbo àwọn tó jẹ́ tìrẹ.”

8 Ábímélékì jí ní àárọ̀ kùtù, ó pe gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sọ gbogbo nǹkan yìí fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gan-an. 9 Ábímélékì wá pe Ábúráhámù, ó sì sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tí o fi fẹ́ fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ tó báyìí jẹ èmi àti àwọn èèyàn mi? Ohun tí o ṣe sí mi yìí ò dáa.” 10 Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí lo ní lọ́kàn tó o fi ṣe báyìí?”+ 11 Ábúráhámù fèsì pé: “Èrò mi ni pé, ‘Ó dájú pé àwọn èèyàn tó wà níbí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n á sì pa mí torí ìyàwó+ mi.’ 12 Àbúrò mi ni lóòótọ́ o, bàbá kan náà ló bí wa, àmọ́ a kì í ṣọmọ ìyá kan náà, mo sì mú un ṣaya.+ 13 Torí náà, nígbà tí Ọlọ́run mú kí n kúrò ní ilé bàbá mi,+ mo sọ fún un pé: ‘Bí o ṣe máa fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ lo ní sí mi nìyí: Gbogbo ibi tí a bá lọ, máa sọ nípa mi pé, “Ẹ̀gbọ́n mi ni.”’”+

14 Ìgbà náà ni Ábímélékì mú àwọn àgùntàn àti màlúù pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sérà ìyàwó rẹ̀ pa dà fún un. 15 Ábímélékì tún sọ pé: “Ilẹ̀ mi nìyí. Ibi tó bá wù ọ́ ni kó o máa gbé níbẹ̀.” 16 Ó sì sọ fún Sérà pé: “Mo fún ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà. Ó jẹ́ àmì pé o ò mọwọ́ mẹsẹ̀* lójú gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ àti lójú gbogbo èèyàn, wọn ò sì ní pẹ̀gàn rẹ mọ́.” 17 Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ sí í rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run sì mú Ábímélékì àti ìyàwó rẹ̀ lára dá, pẹ̀lú àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀, wọ́n sì wá ń bímọ; 18 nítorí Jèhófà ti mú kí gbogbo obìnrin ilé Ábímélékì di àgàn* torí Sérà, ìyàwó+ Ábúráhámù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́