ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Lo àǹfààní tí o ní (1-8)

        • Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi (1)

        • Fún irúgbìn láti àárọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ (6)

      • Gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ lọ́nà tó yẹ (9, 10)

Oníwàásù 11:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Da.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 22:9
  • +Di 15:10, 11; Owe 19:17; Lk 14:13, 14; Heb 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2000, ojú ìwé 21

Oníwàásù 11:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:21; Lk 6:38; 2Kọ 9:7; 1Ti 6:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2000, ojú ìwé 21

Oníwàásù 11:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 20:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!: Bá A Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Àkókò Wa

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 16

Oníwàásù 11:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “egungun tó wà nínú ilé ọlẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 139:15
  • +Job 26:14; Sm 40:5; Onw 8:17; Ro 11:33

Oníwàásù 11:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 9:10; 2Kọ 9:6; Kol 3:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    5/2018, ojú ìwé 16

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2001, ojú ìwé 29-31

    3/1/1993, ojú ìwé 22-23

Oníwàásù 11:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 15

Oníwàásù 11:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 5:18; 8:15
  • +Onw 12:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 15

    8/15/1998, ojú ìwé 9

Oníwàásù 11:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pè ọ́ wá jíhìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 3:17; 12:14; Ro 2:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2004, ojú ìwé 13

    8/15/1998, ojú ìwé 8

Oníwàásù 11:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 25:7; 2Ti 2:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 15

    5/1/2004, ojú ìwé 13

Àwọn míì

Oníw. 11:1Owe 22:9
Oníw. 11:1Di 15:10, 11; Owe 19:17; Lk 14:13, 14; Heb 6:10
Oníw. 11:2Sm 37:21; Lk 6:38; 2Kọ 9:7; 1Ti 6:18
Oníw. 11:4Owe 20:4
Oníw. 11:5Sm 139:15
Oníw. 11:5Job 26:14; Sm 40:5; Onw 8:17; Ro 11:33
Oníw. 11:6Onw 9:10; 2Kọ 9:6; Kol 3:23
Oníw. 11:8Onw 5:18; 8:15
Oníw. 11:8Onw 12:1
Oníw. 11:9Onw 3:17; 12:14; Ro 2:6
Oníw. 11:10Sm 25:7; 2Ti 2:22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 11:1-10

Oníwàásù

11 Fọ́n* oúnjẹ rẹ sí ojú omi,+ torí pé lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, wàá tún rí i.+ 2 Pín in fún àwọn méje tàbí mẹ́jọ pàápàá,+ nítorí o kò mọ àjálù tó máa dé bá ayé.

3 Tí òjò bá ṣú lójú ọ̀run, á rọ̀ sórí ilẹ̀; tí igi kan bá sì ṣubú sí gúúsù tàbí sí àríwá, ibi tí igi náà ṣubú sí, ibẹ̀ ló máa wà.

4 Ẹni tó bá ń wojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn; ẹni tó bá sì ń wo ṣíṣú òjò kò ní kórè.+

5 Bí o ò ṣe mọ bí ẹ̀mí ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú egungun ọmọ tó wà nínú* aboyún,+ bẹ́ẹ̀ lo ò ṣe mọ iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó ń ṣe ohun gbogbo.+

6 Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́;+ nítorí o ò mọ èyí tó máa ṣe dáadáa, bóyá èyí tàbí ìyẹn, ó sì lè jẹ́ àwọn méjèèjì ló máa ṣe dáadáa.

7 Ìmọ́lẹ̀ dùn, ó sì dára kí ojú rí oòrùn. 8 Tí èèyàn bá lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé, kí ó gbádùn gbogbo rẹ̀.+ Àmọ́, ó yẹ kó máa rántí pé àwọn ọjọ́ òkùnkùn lè pọ̀, asán sì ni gbogbo ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.+

9 Máa yọ̀, ìwọ ọ̀dọ́kùnrin, nígbà tí o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa yọ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ. Máa ṣe ohun tí ọkàn rẹ bá sọ, sì máa lọ síbi tí ojú rẹ bá darí rẹ sí; ṣùgbọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ máa dá ọ lẹ́jọ́* lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+ 10 Nítorí náà, mú àwọn ohun tó ń kó ìdààmú báni kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì gbá àwọn ohun tó ń ṣeni léṣe dà nù ní ara* rẹ, torí pé asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀dọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́