ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà

      • Ọlọ́run fìdí ìjọba Dáfídì múlẹ̀ (1, 2)

      • Ìdílé Dáfídì (3-7)

      • Wọ́n ṣẹ́gun àwọn Filísínì (8-17)

1 Kíróníkà 14:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn tó ń mọ ògiri.”

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:6, 8
  • +2Sa 5:11, 12

1 Kíróníkà 14:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:20, 21
  • +2Sa 7:8

1 Kíróníkà 14:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:17
  • +2Sa 5:13-16

1 Kíróníkà 14:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 3:5-9
  • +Lk 3:23, 31
  • +1Ọb 1:47; Mt 1:6

1 Kíróníkà 14:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 11:3
  • +2Sa 5:17; Sm 2:2

1 Kíróníkà 14:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:18, 22; 23:13

1 Kíróníkà 14:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:19-21

1 Kíróníkà 14:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọ̀gá Àwọn Tó Ń Ya Luni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 28:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1991, ojú ìwé 20-21

1 Kíróníkà 14:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:25

1 Kíróníkà 14:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:22-25

1 Kíróníkà 14:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 8:2; Sm 18:34

1 Kíróníkà 14:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:14; Ond 4:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1991, ojú ìwé 21

1 Kíróníkà 14:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:22; Ẹk 39:32
  • +Joṣ 16:10

1 Kíróníkà 14:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:25; 11:25; Joṣ 2:9

Àwọn míì

1 Kíró. 14:11Ọb 5:6, 8
1 Kíró. 14:12Sa 5:11, 12
1 Kíró. 14:2Sm 89:20, 21
1 Kíró. 14:22Sa 7:8
1 Kíró. 14:3Di 17:17
1 Kíró. 14:32Sa 5:13-16
1 Kíró. 14:41Kr 3:5-9
1 Kíró. 14:4Lk 3:23, 31
1 Kíró. 14:41Ọb 1:47; Mt 1:6
1 Kíró. 14:81Kr 11:3
1 Kíró. 14:82Sa 5:17; Sm 2:2
1 Kíró. 14:92Sa 5:18, 22; 23:13
1 Kíró. 14:102Sa 5:19-21
1 Kíró. 14:11Ais 28:21
1 Kíró. 14:12Di 7:25
1 Kíró. 14:132Sa 5:22-25
1 Kíró. 14:14Joṣ 8:2; Sm 18:34
1 Kíró. 14:15Di 23:14; Ond 4:14
1 Kíró. 14:16Jẹ 6:22; Ẹk 39:32
1 Kíró. 14:16Joṣ 16:10
1 Kíró. 14:17Di 2:25; 11:25; Joṣ 2:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kíróníkà 14:1-17

Kíróníkà Kìíní

14 Hírámù+ ọba Tírè rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó kó igi kédárì ránṣẹ́, ó tún rán àwọn oníṣẹ́ òkúta* àti àwọn oníṣẹ́ igi láti kọ́ ilé* fún un.+ 2 Dáfídì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì,+ torí pé Ó ti gbé ìjọba Dáfídì ga nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀ Ísírẹ́lì.+

3 Dáfídì fẹ́ ìyàwó sí i+ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i.+ 4 Orúkọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù+ nìyí: Ṣámúà, Ṣóbábù, Nátánì,+ Sólómọ́nì,+ 5 Íbárì, Élíṣúà, Élípélétì, 6 Nógà, Néfégì, Jáfíà, 7 Élíṣámà, Béélíádà àti Élífélétì.

8 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ pé wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ gbogbo àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì.+ Bí Dáfídì ṣe gbọ́ báyìí, ó lọ gbéjà kò wọ́n. 9 Ìgbà náà ni àwọn Filísínì wọlé wá, wọ́n sì ń kó nǹkan àwọn èèyàn ní Àfonífojì* Réfáímù.+ 10 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún un pé: “Lọ, ó dájú pé màá fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”+ 11 Torí náà, Dáfídì lọ sí Baali-pérásímù,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀. Dáfídì wá sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ ti tipasẹ̀ ọwọ́ mi ya lu àwọn ọ̀tá mi, bí ìgbà tí omi bá ya lu nǹkan.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Baali-pérásímù.* 12 Àwọn Filísínì fi àwọn ọlọ́run wọn sílẹ̀ níbẹ̀, a sì dáná sun+ wọ́n bí Dáfídì ṣe pa á láṣẹ.

13 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá kó nǹkan àwọn èèyàn ní àfonífojì*+ náà. 14 Dáfídì tún wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà.+ 15 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o dojú ìjà kọ wọ́n, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.”+ 16 Torí náà, Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́,+ wọ́n sì pa àwọn ọmọ ogun Filísínì láti Gíbíónì títí dé Gésérì.+ 17 Òkìkí Dáfídì kàn dé gbogbo àwọn ilẹ̀ náà, Jèhófà sì mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa bẹ̀rù rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́