ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Mósè àti Áárónì lọ bá Fáráò (1-5)

      • Wọ́n túbọ̀ fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (6-18)

      • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá Mósè àti Áárónì lẹ́bi (19-23)

Ẹ́kísódù 5:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:5; 9:15, 16
  • +2Ọb 18:28, 35
  • +Ẹk 3:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 6/2020, ojú ìwé 7

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1993, ojú ìwé 3-5

Ẹ́kísódù 5:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:18

Ẹ́kísódù 5:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sábẹ́ àjàgà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:11

Ẹ́kísódù 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:14

Ẹ́kísódù 5:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣọ̀lẹ.”

Ẹ́kísódù 5:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:11

Ẹ́kísódù 5:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:11

Ẹ́kísódù 5:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣọ̀lẹ.”

  • *

    Tàbí “ẹ ti ń ṣọ̀lẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 5:7, 8
  • +Ẹk 5:3

Ẹ́kísódù 5:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú kí á dà bí òórùn burúkú sí Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:9

Ẹ́kísódù 5:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 5:1
  • +Ẹk 5:6, 9
  • +Ẹk 3:8

Àwọn míì

Ẹ́kís. 5:2Ẹk 7:5; 9:15, 16
Ẹ́kís. 5:22Ọb 18:28, 35
Ẹ́kís. 5:2Ẹk 3:19
Ẹ́kís. 5:3Ẹk 3:18
Ẹ́kís. 5:4Ẹk 1:11
Ẹ́kís. 5:7Ẹk 1:14
Ẹ́kís. 5:10Ẹk 1:11
Ẹ́kís. 5:14Ẹk 2:11
Ẹ́kís. 5:17Ẹk 5:7, 8
Ẹ́kís. 5:17Ẹk 5:3
Ẹ́kís. 5:21Ẹk 6:9
Ẹ́kís. 5:23Ẹk 5:1
Ẹ́kís. 5:23Ẹk 5:6, 9
Ẹ́kís. 5:23Ẹk 3:8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 5:1-23

Ẹ́kísódù

5 Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ, kí wọ́n lè ṣe àjọyọ̀ fún mi nínú aginjù.’” 2 Àmọ́ Fáráò sọ pé: “Ta ni Jèhófà,+ tí màá fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu pé kí n jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ?+ Mi ò mọ Jèhófà rárá, mi ò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ.”+ 3 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run àwa Hébérù ti bá wa sọ̀rọ̀. Jọ̀ọ́, a fẹ́ rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ká sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, yóò fi àìsàn kọ lù wá tàbí kó fi idà pa wá.” 4 Ọba Íjíbítì fèsì pé: “Mósè àti Áárónì, kí ló dé tí ẹ fẹ́ mú àwọn èèyàn yìí kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ pa dà sẹ́nu iṣẹ́* yín!”+ 5 Fáráò tún sọ pé: “Ẹ wo bí àwọn èèyàn yìí ṣe pọ̀ tó nílẹ̀ yìí, ẹ wá fẹ́ dá iṣẹ́ wọn dúró!”

6 Ọjọ́ yẹn gan-an ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ àti àwọn olórí wọn pé: 7 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún àwọn èèyàn náà ní pòròpórò mọ́ láti fi ṣe bíríkì.+ Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ máa wá a fúnra wọn. 8 Àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé iye bíríkì tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni wọ́n ṣì ń ṣe. Ẹ ò gbọ́dọ̀ dín in kù, torí wọ́n ti ń dẹwọ́.* Ìyẹn ni wọ́n ṣe ń pariwo pé, ‘A fẹ́ máa lọ, a fẹ́ lọ rúbọ sí Ọlọ́run wa!’ 9 Ẹ jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára, ẹ sì jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí kí wọ́n má bàa fetí sí irọ́.”

10 Torí náà, àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́+ àti àwọn olórí wọn lọ bá àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Fáráò sọ nìyí, ‘Mi ò ní fún yín ní pòròpórò kankan mọ́. 11 Ẹ lọ máa wá pòròpórò tí ẹ máa lò fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti lè rí i, àmọ́ iṣẹ́ yín ò ní dín kù rárá.’” 12 Àwọn èèyàn náà wá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì láti wá pòròpórò tí wọ́n máa lò dípò èyí tí wọ́n ń fún wọn tẹ́lẹ̀. 13 Àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ sì ń sọ fún wọn pé: “Kálukú yín gbọ́dọ̀ máa parí iṣẹ́ rẹ̀ lójoojúmọ́, bí ìgbà tí à ń fún yín ní pòròpórò tẹ́lẹ̀.” 14 Bákan náà, wọ́n lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Fáráò fi ṣe olórí.+ Wọ́n bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí iye bíríkì tí ẹ ṣe kò tó iye tí ẹ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀? Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lánàá, ó tún ṣẹlẹ̀ lónìí.”

15 Àwọn olórí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá lọ bá Fáráò, wọ́n sì ń ṣàròyé pé: “Kí ló dé tí ò ń ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ báyìí? 16 Wọn ò fún àwa ìránṣẹ́ rẹ ní pòròpórò, síbẹ̀ wọ́n ń sọ fún wa pé, ‘Ẹ máa ṣe bíríkì!’ Wọ́n lu àwa ìránṣẹ́ rẹ, àmọ́ àwọn èèyàn rẹ ló lẹ̀bi.” 17 Àmọ́ ó fèsì pé: “Ẹ ti ń dẹwọ́,* ẹ ti ń dẹwọ́!*+ Torí ẹ̀ lẹ ṣe ń sọ pé, ‘A fẹ́ máa lọ, a fẹ́ lọ rúbọ sí Jèhófà.’+ 18 Ó yá, ẹ pa dà sẹ́nu iṣẹ́! Ẹ ò ní rí pòròpórò kankan gbà mọ́, àmọ́ ẹ ṣì gbọ́dọ̀ máa ṣe iye bíríkì tó yẹ kí ẹ ṣe.”

19 Àwọn olórí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rí i pé àwọn ti wọ wàhálà, torí àṣẹ tí Fáráò pa pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dín iye bíríkì tí ẹ̀ ń ṣe lójúmọ́ kù rárá.” 20 Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ bá Mósè àti Áárónì, tí wọ́n ń dúró dè wọ́n kí wọ́n lè pàdé wọn bí wọ́n ṣe ń jáde lọ́dọ̀ Fáráò. 21 Ni wọ́n bá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Kí Jèhófà bojú wò yín kó sì ṣèdájọ́, torí ẹ ti mú kí Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kórìíra wa,* ẹ sì ti fi idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá.”+ 22 Mósè bá yíjú sí Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà, kí ló dé tí o fìyà jẹ àwọn èèyàn yìí? Kí nìdí tí o fi rán mi? 23 Látìgbà tí mo ti lọ bá Fáráò, tí mo sì sọ̀rọ̀ lórúkọ rẹ+ ló ti túbọ̀ ń fìyà jẹ àwọn èèyàn yìí,+ o ò sì gba àwọn èèyàn rẹ sílẹ̀ rárá.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́