ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀ pé Ahasáyà máa kú (1-18)

2 Àwọn Ọba 1:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 19:36, 37; 2Sa 8:2; Sm 60:8

2 Àwọn Ọba 1:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:2, 3; 1Sa 5:10
  • +2Ọb 1:16

2 Àwọn Ọba 1:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run Mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 17:1; 18:36
  • +Ais 8:19; Jer 2:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1697

2 Àwọn Ọba 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 10:13, 14

2 Àwọn Ọba 1:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:19; Sek 13:4; Heb 11:32, 37
  • +Mt 3:4

2 Àwọn Ọba 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:1

2 Àwọn Ọba 1:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:1; 16:35; Lk 9:54; Jud 7

2 Àwọn Ọba 1:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “jẹ́ kí ọkàn mi àti ọkàn.”

2 Àwọn Ọba 1:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

2 Àwọn Ọba 1:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:2, 3
  • +2Ọb 1:3

2 Àwọn Ọba 1:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, àbúrò Ahasáyà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 3:1; 9:22
  • +2Ọb 8:16

2 Àwọn Ọba 1:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:51

Àwọn míì

2 Ọba 1:1Jẹ 19:36, 37; 2Sa 8:2; Sm 60:8
2 Ọba 1:2Joṣ 13:2, 3; 1Sa 5:10
2 Ọba 1:22Ọb 1:16
2 Ọba 1:31Ọb 17:1; 18:36
2 Ọba 1:3Ais 8:19; Jer 2:11
2 Ọba 1:61Kr 10:13, 14
2 Ọba 1:81Ọb 19:19; Sek 13:4; Heb 11:32, 37
2 Ọba 1:8Mt 3:4
2 Ọba 1:9Di 33:1
2 Ọba 1:10Nọ 11:1; 16:35; Lk 9:54; Jud 7
2 Ọba 1:16Joṣ 13:2, 3
2 Ọba 1:162Ọb 1:3
2 Ọba 1:172Ọb 3:1; 9:22
2 Ọba 1:172Ọb 8:16
2 Ọba 1:181Ọb 22:51
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 1:1-18

Àwọn Ọba Kejì

1 Lẹ́yìn ikú Áhábù, Móábù+ ṣọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì.

2 Nígbà náà, Ahasáyà já bọ́ láti ibi asẹ́ tó wà ní yàrá òrùlé rẹ̀ ní Samáríà, ó sì fara pa. Torí náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì+ bóyá ibi tí mo fi ṣèṣe yìí máa san.”+ 3 Àmọ́, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Èlíjà*+ ará Tíṣíbè pé: “Gbéra, lọ pàdé àwọn òjíṣẹ́ ọba Samáríà, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni, tí ẹ fi ń lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì?+ 4 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.”’” Èlíjà sì bá tirẹ̀ lọ.

5 Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi pa dà?” 6 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ọkùnrin kan wá pàdé wa, ó sọ fún wa pé, ‘Ẹ pa dà sọ́dọ̀ ọba tó rán yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni, tí o fi ní kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì? Nítorí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’”’”+ 7 Ó wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Báwo ni ọkùnrin tó wá pàdé yín, tó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún yín ṣe rí?” 8 Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọkùnrin náà wọ aṣọ onírun,+ ó sì de àmùrè awọ mọ́ ìbàdí rẹ̀.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Èlíjà ará Tíṣíbè ni.”

9 Ọba wá rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Nígbà tó lọ bá Èlíjà, ó rí i tó jókòó sórí òkè. Ó sọ fún un pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ọba sọ pé, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá.’” 10 Àmọ́ Èlíjà dá olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun náà lóhùn pé: “Ó dáa, tó bá jẹ́ pé èèyàn Ọlọ́run ni mí lóòótọ́, kí iná bọ́ láti ọ̀run,+ kó sì jó ìwọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ run.” Ni iná bá bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀ run.

11 Nítorí náà, ọba tún rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun míì sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Ó lọ, ó sì sọ fún un pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá kíákíá.’” 12 Àmọ́ Èlíjà dá wọn lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ pé èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni mí lóòótọ́, kí iná bọ́ láti ọ̀run, kó sì jó ìwọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ run.” Ni iná Ọlọ́run bá bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀ run.

13 Lẹ́yìn náà, ọba rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun kẹta sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Àmọ́ olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun kẹta jáde lọ, ó sì tẹrí ba lórí ìkúnlẹ̀ níwájú Èlíjà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojú rere sí òun, ó ní: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí* àádọ́ta (50) ìránṣẹ́ rẹ yìí ṣeyebíye lójú rẹ. 14 Iná ti bọ́ láti ọ̀run, ó sì ti jó àwọn olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun méjì tó ṣáájú run pẹ̀lú àádọ́ta (50) wọn, ṣùgbọ́n ní báyìí, jẹ́ kí ẹ̀mí* mi ṣeyebíye lójú rẹ.”

15 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Èlíjà pé: “Sọ̀ kalẹ̀ tẹ̀ lé e. Má bẹ̀rù rẹ̀.” Torí náà, ó dìde, ó sọ̀ kalẹ̀, ó sì tẹ̀ lé e lọ sọ́dọ̀ ọba. 16 Èlíjà wá sọ fún ọba pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘O rán àwọn òjíṣẹ́ pé kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì.+ Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni?+ Kí ló dé tí o ò fi wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀? Torí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’” 17 Torí náà, ó kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ. Àmọ́ torí pé kò ní ọmọkùnrin kankan, Jèhórámù*+ jọba ní ipò rẹ̀, ní ọdún kejì Jèhórámù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọba Júdà.

18 Ní ti ìyókù ìtàn Ahasáyà+ àti ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́