ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Orin arò torí àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì (1-14)

Ìsíkíẹ́lì 19:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”

Ìsíkíẹ́lì 19:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láàárín àwọn ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Ìsíkíẹ́lì 19:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:1

Ìsíkíẹ́lì 19:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:31-34; 2Kr 36:4; Jer 22:11, 12

Ìsíkíẹ́lì 19:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 22:17

Ìsíkíẹ́lì 19:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 28:15

Ìsíkíẹ́lì 19:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “bí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 80:8; Ais 5:7

Ìsíkíẹ́lì 19:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ọ̀pá.”

Ìsíkíẹ́lì 19:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:5; Isk 15:6
  • +2Ọb 23:34; 24:6; 25:5-7
  • +Di 32:22; Isk 15:4

Ìsíkíẹ́lì 19:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:48; Jer 17:5, 6; 52:27

Ìsíkíẹ́lì 19:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 17:16, 18

Àwọn míì

Ìsík. 19:32Kr 36:1
Ìsík. 19:42Ọb 23:31-34; 2Kr 36:4; Jer 22:11, 12
Ìsík. 19:6Jer 22:17
Ìsík. 19:7Owe 28:15
Ìsík. 19:10Sm 80:8; Ais 5:7
Ìsík. 19:12Ais 5:5; Isk 15:6
Ìsík. 19:122Ọb 23:34; 24:6; 25:5-7
Ìsík. 19:12Di 32:22; Isk 15:4
Ìsík. 19:13Di 28:48; Jer 17:5, 6; 52:27
Ìsík. 19:14Isk 17:16, 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 19:1-14

Ìsíkíẹ́lì

19 “Kí o kọ orin arò* nípa àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, 2 kí o sì sọ pé,

‘Ta ni ìyá rẹ? Abo kìnnìún láàárín àwọn kìnnìún.

Ó dùbúlẹ̀ sáàárín àwọn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

 3 Ó tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di ọmọ kìnnìún tó lágbára.+

Ọmọ náà kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa ẹran jẹ,

Ó tún ń pa èèyàn jẹ.

 4 Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n mú un nínú ihò wọn,

Wọ́n sì fi ìkọ́ fà á wá sí ilẹ̀ Íjíbítì.+

 5 Ìyá rẹ̀ dúró dè é, nígbà tó yá, ó rí i pé kò sírètí pé ó máa pa dà.

Torí náà, ó mú òmíràn nínú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì rán an jáde bí ọmọ kìnnìún tó lágbára.

 6 Òun náà rìn káàkiri láàárín àwọn kìnnìún, ó sì di ọmọ kìnnìún tó lágbára.

Ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa ẹran jẹ, ó sì tún ń pa èèyàn jẹ.+

 7 Ó ń rìn kiri láàárín àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò, ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro,

Débi pé ìró bó ṣe ń ké ramúramù gba ilẹ̀ tó ti di ahoro náà kan.+

 8 Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láwọn agbègbè tó yí i ká wá a wá kí wọ́n lè fi àwọ̀n mú un,

Wọ́n sì mú un nínú ihò wọn.

 9 Wọ́n fi ìkọ́ gbé e sínú àhámọ́, wọ́n sì gbé e wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì.

Ibẹ̀ ni wọ́n sé e mọ́, kí wọ́n má bàa gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì.

10 Ìyá rẹ dà bí àjàrà+ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ,* èyí tí wọ́n gbìn sétí omi.

Ọ̀pọ̀ omi náà mú kó so èso, kó sì pẹ̀ka rẹpẹtẹ.

11 Ó wá ní àwọn ẹ̀ka* tó lágbára, tó ṣeé fi ṣe ọ̀pá àṣẹ àwọn alákòóso.

Ó dàgbà, ó sì ga ju àwọn igi yòókù,

Wọ́n sì wá rí i, torí pé ó ga, ewé rẹ̀ sì pọ̀ yanturu.

12 Àmọ́ a fà á tu tìbínútìbínú,+ a sì jù ú sórí ilẹ̀,

Atẹ́gùn ìlà oòrùn sì mú kí èso rẹ̀ gbẹ.

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó lágbára ya dà nù, wọ́n gbẹ,+ iná sì jó wọn run.+

13 Inú aginjù ni wọ́n wá gbìn ín sí,

Ní ilẹ̀ tó gbẹ, tí kò lómi.+

14 Iná ràn látorí àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ó sì jó àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ àti àwọn èso rẹ̀,

Kò sì wá sí ẹ̀ka tó lágbára mọ́ lórí rẹ̀, kò sí ọ̀pá àṣẹ fún àwọn alákòóso.+

“‘Orin arò nìyẹn, yóò sì máa jẹ́ orin arò.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́