Náhúmù
Máa ṣọ́ àwọn ibi olódi.
Máa ṣọ́ ọ̀nà.
Gbára dì,* kí o sì sa gbogbo agbára rẹ.
2 Nítorí Jèhófà yóò dá ògo Jékọ́bù pa dà,
Yóò dá a pa dà sí ògo Ísírẹ́lì,
Nítorí àwọn apanirun ti pa wọ́n run;+
Wọ́n sì ti pa àwọn ọ̀mùnú wọn run.
3 Apata àwọn ọkùnrin rẹ̀ alágbára ti di pupa,
Aṣọ àwọn jagunjagun rẹ̀ ti rẹ̀ dòdò.
Àwọn irin tí wọ́n dè mọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ń kọ mànà bí iná
Ní ọjọ́ tó ń múra ogun sílẹ̀,
Ó sì ń ju àwọn ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi igi júnípà ṣe fìrìfìrì.
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń sáré àsápajúdé ní ojú ọ̀nà.
Wọ́n ń sáré sókè-sódò ní àwọn ojúde ìlú.
Wọ́n ń mọ́lẹ̀ yòò bí iná ògùṣọ̀, wọ́n sì ń kọ mànà bíi mànàmáná.
5 Ó máa pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀.
Wọ́n á kọsẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ.
Wọ́n á sáré lọ sí ibi ògiri rẹ̀;
Wọ́n á sì gbé ohun ìdènà kalẹ̀.
7 A ti pá a láṣẹ:* Wọ́n ti tú u sí ìhòòhò,
Wọ́n gbé e lọ, àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ dárò rẹ̀;
Wọ́n ń ké bí àdàbà bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ lu àyà* wọn.
8 Láti ọjọ́ tí Nínéfè+ ti wà ló ti dà bí adágún omi,
Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń sá lọ.
“Ẹ dúró! Ẹ dúró!”
Àmọ́ kò sí ẹni tó yíjú pa dà.+
9 Ẹ kó fàdákà, ẹ kó wúrà!
Àwọn ìṣúra rẹ̀ kò lópin.
Onírúurú ohun iyebíye ló kún inú rẹ̀.
10 Ìlú náà ti ṣófo, ó ti di ahoro, ó sì ti pa run!+
Ìbẹ̀rù ti jẹ́ kí ọkàn wọn domi, orúnkún wọn ń gbọ̀n, gbogbo ara ń ro wọ́n;
Gbogbo ojú wọn sì pọ́n.
11 Ibo ni àwọn kìnnìún ń gbé,+ níbi tí àwọn ọmọ kìnnìún* ti ń jẹun,
Níbi tí kìnnìún ti ń kó ọmọ rẹ̀ jáde,
Tí ẹnì kankan ò sì dẹ́rù bà wọ́n?
12 Kìnnìún ń fa ọ̀pọ̀ ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀
Ó sì ń fún ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀.
Ó kó ẹran tí ó pa kún inú ihò rẹ̀,
Àti èyí tó fà ya kún ibùgbé rẹ̀.
13 “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+
“Màá mú kí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ jóná pátápátá,+
Idà yóò sì pa àwọn ọmọ kìnnìún* rẹ run.
Mi ò ní jẹ́ kí o mú àwọn èèyàn bí ẹran mọ́ ní ayé,
A kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn òjíṣẹ́ rẹ mọ́.”+