ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 39
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jósẹ́fù ní ilé Pọ́tífárì (1-6)

      • Jósẹ́fù ò gbà fún ìyàwó Pọ́tífárì (7-20)

      • Jósẹ́fù ṣẹ̀wọ̀n (21-23)

Jẹ́nẹ́sísì 39:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:17; Iṣe 7:9
  • +Jẹ 37:36
  • +Jẹ 17:20; 37:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 12-13

Jẹ́nẹ́sísì 39:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:31; Heb 13:6

Jẹ́nẹ́sísì 39:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:27

Jẹ́nẹ́sísì 39:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 39:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 39:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:24; 20:3, 6; Sm 51:àkọlé; 51:4; Mk 10:7, 8; Heb 13:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 41

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2018, ojú ìwé 26

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2017, ojú ìwé 4-5

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 14

    11/1/2013, ojú ìwé 9

    2/15/2013, ojú ìwé 4

    10/15/2007, ojú ìwé 23-24

    6/15/2006, ojú ìwé 28-29

    1/15/2004, ojú ìwé 29

    12/1/2003, ojú ìwé 20

    11/1/2000, ojú ìwé 9-10

    9/1/1998, ojú ìwé 5

    10/15/1997, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 39:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2015, ojú ìwé 16

    11/1/2014, ojú ìwé 14

Jẹ́nẹ́sísì 39:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 41

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 14

Jẹ́nẹ́sísì 39:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:17, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 14-15

Jẹ́nẹ́sísì 39:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 40:2, 3; Sm 105:19; Iṣe 7:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2015, ojú ìwé 12

    11/1/2014, ojú ìwé 15

    5/15/2002, ojú ìwé 14-17

Jẹ́nẹ́sísì 39:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 39:6

Jẹ́nẹ́sísì 39:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:22, 25; Iṣe 7:9, 10

Àwọn míì

Jẹ́n. 39:1Sm 105:17; Iṣe 7:9
Jẹ́n. 39:1Jẹ 37:36
Jẹ́n. 39:1Jẹ 17:20; 37:25
Jẹ́n. 39:2Ro 8:31; Heb 13:6
Jẹ́n. 39:5Jẹ 30:27
Jẹ́n. 39:9Jẹ 2:24; 20:3, 6; Sm 51:àkọlé; 51:4; Mk 10:7, 8; Heb 13:4
Jẹ́n. 39:20Sm 105:17, 18
Jẹ́n. 39:21Jẹ 40:2, 3; Sm 105:19; Iṣe 7:9
Jẹ́n. 39:22Jẹ 39:6
Jẹ́n. 39:23Jẹ 49:22, 25; Iṣe 7:9, 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 39:1-23

Jẹ́nẹ́sísì

39 Wọ́n wá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì,+ Pọ́tífárì+ ará Íjíbítì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò àti olórí ẹ̀ṣọ́ sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tó mú un lọ síbẹ̀. 2 Àmọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.+ Ìyẹn mú kó ṣàṣeyọrí, ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ ará Íjíbítì sì fi ṣe alábòójútó ilé rẹ̀. 3 Ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ àti pé Jèhófà ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe yọrí sí rere.

4 Jósẹ́fù máa ń rí ojúure rẹ̀, ó sì di ìránṣẹ́ Pọ́tífárì fúnra rẹ̀. Ó wá fi ṣe olórí ilé rẹ̀, ó sì ní kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní òun. 5 Látìgbà tí ọ̀gá rẹ̀ ti fi ṣe olórí ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun tó ní, Jèhófà ń bù kún ilé ará Íjíbítì náà torí Jósẹ́fù. Jèhófà sì bù kún gbogbo ohun ìní Pọ́tífárì nílé lóko.+ 6 Nígbà tó yá, ó fi gbogbo ohun tó ní sí ìkáwọ́ Jósẹ́fù, kò sì da ara rẹ̀ láàmú nípa ohunkóhun àfi oúnjẹ tó ń jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jósẹ́fù taagun, ó sì rẹwà.

7 Lẹ́yìn náà, ojú ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù kò kúrò lára rẹ̀, ó sì ń sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.” 8 Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà, ó sì sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá mi kì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò nínú ilé, ó sì ti fa gbogbo ohun tó ní lé mi lọ́wọ́. 9 Kò sẹ́ni tó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, kò sì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi àyàfi ìwọ, torí pé ìwọ ni ìyàwó rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?”+

10 Ojoojúmọ́ ló ń bá Jósẹ́fù sọ ọ́, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà rárá láti bá a sùn tàbí kó wà pẹ̀lú rẹ̀. 11 Lọ́jọ́ kan tí Jósẹ́fù wọnú ilé lọ ṣiṣẹ́ rẹ̀, kò sí ìránṣẹ́ ilé kankan nínú ilé. 12 Obìnrin náà di aṣọ rẹ̀ mú, ó sì sọ pé: “Wá bá mi sùn!” Àmọ́ Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì sá jáde. 13 Bí obìnrin náà ṣe rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, tó sì ti sá jáde, 14 ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe àwọn èèyàn tó wà nílé, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ó mú ọkùnrin Hébérù yìí wá sọ́dọ̀ wa kó lè fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wá bá mi, ó fẹ́ bá mi sùn, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í ké tantan. 15 Bó ṣe wá rí i pé mò ń pariwo, tí mo sì ń kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 16 Lẹ́yìn náà, obìnrin náà fi aṣọ Jósẹ́fù sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ títí ọ̀gá rẹ̀ fi dé sí ilé.

17 Ó sọ ohun kan náà fún un, ó ní: “Ìránṣẹ́ Hébérù tí o mú wá sọ́dọ̀ wa wá bá mi kó lè fi mí ṣe ẹlẹ́yà. 18 Àmọ́ gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, tí mo sì kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 19 Gbàrà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí ìránṣẹ́ rẹ ṣe sí mi nìyí,” inú bí i gan-an. 20 Ni ọ̀gá Jósẹ́fù bá ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí wọ́n ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí, ó sì wà níbẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n.+

21 Àmọ́ Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀, ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí i, ó sì ń mú kó rí ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n+ náà. 22 Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wá fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, òun ló sì máa ń rí sí i pé wọ́n ṣe gbogbo iṣẹ́ tó wà níbẹ̀.+ 23 Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ò yẹ Jósẹ́fù lọ́wọ́ wò rárá, torí Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, Jèhófà sì ń mú kí gbogbo ohun tó bá ṣe yọrí sí rere.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́